A fún Gómìnà Akeredolu ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́ta láti padà sí ọ́fíìsì l'Ondo - PDP yarí

Awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu PDP n'ipinlẹ Ondo ti fun gomina ipinlẹ naa, Oluwarotimi Akeredolu, ni gbedeke ọjọ mẹta lati pada si ipinlẹ naa ti ko ba fẹẹ koju iwọde ifẹhonuhan to lagbara.
Awọn ọdọ ọun lo sọ ọrọ yii loruko ọfiisi apapọ ẹgbẹ naa nilu Akure to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ondo.
Awọn ọdọ yii ti wọn gbero lati ṣe iwọde alalaafia lonii ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa lati beere fun ipada wọṣẹ gomina Akeredolu ni wọn ko raye lati rin kiri igboro latari bi awọn agbofinro ṣe se wọn mọ ọfiisi wọn.
Ẹni to sọrọ lorukọ awọn ọdọ, Tayo Oluyi, ni awọn ko le gba ki gomina Akeredolu o maa ṣejọba lọ lẹyin odi.
Oluyi wi pe “gbogbo aye lo mọ pe lati bi oṣu diẹ sẹyin ni ko ti si ijọba gidi nipinlẹ Ondo ti gomina ti lọ gba itọju loke okun, ti igbakeji rẹ si n dele fun un lai ni ipa kankan ninu iṣejọba.
O wa jọ wa loju pe lati bii ọjọ mejilelọgbọn ti wọn ti ni gomina Akeredolu pada si orilẹ ede Naijiria, a ko tii fi oju ri i nipinlẹ Ondo.
Bawo ni gomina yoo ṣe wa nilẹ yi lati oṣu kan o le ọjọ diẹ sẹyin ti ko si nii yọju si ipinlẹ ti wọn ti dibo yan an sipo gomina.




Eyi n ko ipalara ba iṣejọba, to si tun n mu inira ba awọn olugbe ipinlẹ yii.
Lonii, a fun gomina Akeredolu ni wakati mẹrinlelogun lati ba gbogbo olugbe ipinlẹ yii sọrọ, ko si tun yọju si ipinlẹ yii laarin ọjọ mẹta.
Ti Akeredolu ba kọ lati tẹle awọn gbedeke yii, gbogbo ọmọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ yii yo bọ si igboro lati gbogbo popona titi di igba ti yoo yọju si wa.”
''A ko mọ idi tawọn ọlọpaa fi ti ọfiisi wa''
Oluyi wa kesi ọga agba ajọ ọlọpaa lorilẹ ede Naijiria, Kayode Egbetokun, lati fi ewe ọmọ mọ kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiodun Asabi, leti lori igbesẹ to gbe lati ti ọfiisi ẹgbẹ naa pa.
Awọn ọlọpaa lo ya bo ọfiisi apapọ ẹgbẹ ọhun to wa ni Alagbaka nilu Akure lati nkan bii aago mẹfa aarọ ọjọ Aje.
Wamuwamu ni awọn ọlọpaa ọun ro siwaju ọfiisi naa ti wọn ko si gba ẹnikẹni laaye lati wọle.
Oluyi wi pe “awa kii ṣe oni jagidijagan, bẹẹ ni ko si ẹnikẹni ninu wa to ni ohun ija kankan lọwọ.
A ko waa mọ idi tawọn ọlọpaa fi wi pe a ko nii le wọle si ọfiisi yii ati pe ko si aaye fun wa lati ṣe iwọde ti a fẹẹ ṣe.
Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, Kennedy Peretei, ṣe alaye fun BBC pe iyalẹnu lo jẹ fun awọn lati ri ọgọọrọ awọn ọlọpaa niwaju ọfiisi wọn lai si laasigbo kankan to n waye nibẹ.
Peretei wi pe “ohun itiju ni pe awọn ọlọpaa le pọ to yi lati diwa lọna ati wọle si ọfiisi wa.
“Ni tootọ la kọwe si ajọ ọlọpaa lati fi to wọn leti pe ifẹhonuhan yoo wa loni ki wọn si le pese aabo to jọju fun wa.
O ya wa lẹnu lati ri pe kaka ki wọn waa pese aabo fun wa, niṣe ni wọn waa dunkoko mọ wa, ti wọn si n gbiyanju lati ko jinnijinni bo wa.
Oriṣiriiṣi ọkọ ni wọn ko wa lati di ọna mọ wa pẹlu ọlọpaa to to ọọdunrun lai kii ṣe pe awọn ni wọn n ba wa san owo ọfiisi naa.
Lẹyin ọpọlọpọ atotonu ni wọn gba ki awa kan wọle amo ti wọn le pupọ ninu awọn oṣiṣẹ wa pada ti wọn ko si tun gba ki awọn ọdọ to fẹẹ ṣe ifẹhonuhan naa wọle.''















