'Ifá ló yẹ kí a máa lò láti fi yan àwọn olóṣèlú tí a bá fẹ́ yan adarí rere'

Ọpọn Ifa

Oríṣun àwòrán, Other

Aare Onikoyi ilẹ̀ Yorùbá, Otunba Tomori Williams ti rọ àwọn àgbààgbà àti adarí nílẹ̀ Yorùbá láti máa tẹ̀lé àṣà àti ìṣẹ̀ṣe nípa ṣíṣe àyẹ̀wò lọ́wọ́ Ifa kí wọ́n tó yan olórí àtàwọn olóṣèlú sípò.

Williams pàrọwà yìí nígbà tó gbàlejò ẹgbẹ́ Agbekoya ilẹ̀ Nàìjíríà, èyí tí ààrẹ wọn, Kamorudeen Okikiola ṣe àbẹ̀wò sí lọ́jọ́ Àìkú ní ìpínlẹ̀ Eko.

Aare Onikoyi wòye pé tí àwọn adarí àṣà ilẹ̀ Yorùbá bá máa ń kàn sí Ifa kí wọ́n tó yan olórí, yóò máa ṣe atọ́nà fún yíyan adarí rere.

Ó ní kíkàn sí Ifa yóò fòpin sí ọ̀pọ̀ ìṣòro, tí yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn tó tọ́ wà nípò.

Bákan náà ló rọ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá àtàwọn lọ́balọ́ba láti máa kópa tó lóòrìn nínú àwọn ètò tó máa gbé àṣà Yorùbá lárugẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ààrẹ ẹgbẹ́ Agbekoya, Kamorudeen Okikiola ní àwọn fẹ́ ṣe ayẹyẹ ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n tí àwọn ti dá ẹgbẹ́ náà láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò bí ẹgbẹ́ náà ń ṣiṣẹ́ sí.

Okikiola ní ayẹyẹ ọ̀hún yóò tún fún àwọn ni àǹfàní láti sọ̀rọ̀ lórí bí oúnjẹ ṣe máa pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti mú kí ọrọ̀ ajé rẹ̀ dúró ire.

Ó fi kun pé ọ̀rọ̀ àwọn ìlú tó wà ní ìgbèríko náà jẹ́ ohun tí àwọn máa gbé yẹ̀wò níbi ètò náà.

Yàtọ̀ sí ààrẹ ẹgbẹ́ Agbekoya, akọ̀wé àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà àtàwọn olóyè ẹgbẹ́ míì ló kópa níbi ìpàdé náà.