Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun sọ̀rọ̀ lórí àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì mẹ́ta tó dákú níbi àyẹ̀wò orúkọ

Aworan oṣiṣẹfẹyinti to daku l'Osun

Oríṣun àwòrán, Other

Ijọba ipinle Osun ti ṣọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹfẹyinti ti wọn ni ipenija kan tabi ti wọn n ṣe aisan ni wọn yoo lanfaani lati se ayewo iwe wọn lori foonu.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti mẹta ninu awọn oṣiṣẹfẹyinti nipinlẹ Osun daku niluu Osogbo lọjọ Aje nibi ti wọn ti n ṣe ayẹwo orukọ wọn.

Kọmiṣọnna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ, Họnọrebu Oluomo Kolapo Alimi lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ijọba ipinlẹ Osun.

O ni eleyii maa din bi ero se maa n pọ nile ijọba ati pe o maa din wahala awọn arugbo ku.

O tun fi kun pe awọn oṣiṣẹ fẹyinti ti wọn ko si ipinlẹ Osun lọwọlọwọ naa maa ni anfaani lati ṣe ayẹwo wọn lori ẹrọ ibanisọrọ alagbeka.

Kọmiṣọnna ni awọn oṣiṣẹ fẹyinti ti wọn wa loke okun maa ṣe ayẹwo ti wọn lati pasẹ ipe lori ẹrọ foonu oni fidio.

Igbimọ to n risi ọrọ awọn osisẹ Ifẹhinti sọ pe awọn nireti pe ki wọn fi gbogbo awọn iwe ẹri wọn papaa julọ aworan oṣisẹ ifẹhinti kọọkan ṣọwọ si awọn alamojuto wọn fun irọrun idanimọ wọn lakoko ti wọn ba n yẹ awọn iwe wọn wo ni gbati wọn ba pe wọn lori ago.

Òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì mẹ́ta dákú níbi àyẹ̀wò orúkọ fún owó ‘Pension’ l’Osun

Awọn oṣiṣẹfẹyinti mẹta lo daku lasiko ayẹwo orukọ awọn oṣiṣẹfẹyinti to waye niluu Osogbo, olu ilu ipinlẹ Ọṣun lọjọ Aje.

Ohun ti a gbọ ni pe ọpẹlọpẹ titaraṣaṣa awọn oṣiṣẹ eto ilera ẹka ọkọ itọju alaisan, (Osun Ambulance Service) lo doola ẹmi awọn oṣiṣẹfẹyinti naa.

Iṣẹlẹ yii la gbọ wi pe o fa ikayasoke laarin awọn oṣiṣẹfẹyinti to wa nibi eto naa.

Bi wọn ṣe n sa kijokijo lati doola awọn akẹgbẹ wọn to daku naa.

Pupọ awọn oṣiṣẹfẹyinti naa ti a gbọ wi pe wọn to ẹgbẹrun meji niye ni wọn ti dagba ti ilera ko si fi bẹẹ ji pepe fun wọn.

Pupọ ninu wọn ti okun wọn ko gbe diduro lasiko ayẹwo naa ni wọn sun silẹ, kaakiri agbegbe ibudo ayẹwo orukọ naa.

Aworanawọn oṣiṣẹfẹyinti naa
Aworanawọn oṣiṣẹfẹyinti naa

Ohun ti a gbọ lat’ọdọ awọn iwe iroyin abẹle nilu Oshogbo ni pe pupọ awọn oṣiṣẹfẹyinti naa ni wọn koro oju si ohun ti wọn pe ni iwa aibikita awọn to wa nidi kokari eto ayẹwo ọhun.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹfẹyinti ni awọn fọwọsi eto ayẹwo orukọ naa ṣugbọn...

Aworanawọn oṣiṣẹfẹyinti naa

Ọkan lara awọn oṣiṣẹfẹyinti ipinlẹ Ọsun naa to pe orukọ ara rẹ ni Samuel Aduroja bu ẹnu atẹ lu ohun ti oju awọn akẹgbẹ rẹ ri nibi eto naa

O ni lootọ ijọba ipinlẹ naa lo ṣe agbejalẹ eto ayẹwo ọhun, eyi to ni 8nu awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹfẹyinti pẹlu sun si.

Amọṣa alagba Aduroja ṣalaye pe iba dara ki wọn eto naa rọ awọn lọrun ju bo ṣe ri lọwọlọwọ.

Ọpọ awọn oṣiṣẹfẹyinti naa lo jẹ pe awọn ọmọ ati mọlẹbi wọn miran lo gbe wọn de ibudo ayẹwo naa.