''Díẹ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì tó dákú l'Osun ṣì ń gba ìtójú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn''

Aworan awọn oṣiṣẹfẹyinti l'Osun

Awọn oṣiṣẹfẹyinti nipinlẹ Osun ti sọ fun BBC Yoruba pe kayefi lo jẹ fún awọn nigba ti ìjọba Gomina Ademola Adeleke sọ fún pe ki wọn wa fún ayẹwo orukọ.

Ọgbẹni Yemi Lawal ẹni tó jẹ́ olórí àwọn òṣìṣẹ́ feyinti l'Osun ni awọn kò gbọ iru rẹ rí lásìkò àwọn ìjọba to kọjá ni ipinlẹ Osun.

Ọgbẹni Lawal ni awọn ti ranṣẹ padà si ijọba wi pe ko le ṣeeṣe.

Olori awọn òṣìṣẹ́ feyinti tún ṣàlàyé pé àwọn tí ranse tẹlẹ sì gbogbo òṣìṣẹ́ feyinti pe ki wọn ma lọ fun ayẹwo na.

Ṣùgbọ́n o ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ lo kọ eti ikun si ọ̀rọ̀ náà.

''Òtítọ́ ni pe díẹ̀ lara awon òṣìṣẹ́ feyinti ṣubú lulẹ lasiko ti wọn n ṣe ayẹwo náà.

Díẹ̀ lara wọn sì wa ni ile iwosan tí wọn n gba itọju lọ́wọ́,'' Ọgbẹni Lawal lo sọ bẹẹ.

Ijọba Osun fesi

Ikọ BBC Yoruba kan sì Rasheed Olawale ẹni tó jẹ́ agbenuso fún Gómìnà Ademola Adeleke lori ọrọ naa.

Ọgbẹni Olawale sàlàyé pe ko si ẹni to ni ki àwọn òṣìṣẹ́ feyinti wá fún ayẹwo ni àkókò yí rara.

O ni gómìnà Adeleke tí se ìpàdé pọ pẹlu awọn òṣìṣẹ́ feyinti ati awọn alaba sise pọ rẹ lati rí pe iru ìṣẹ̀lẹ̀ náà ko ni waye mọ rara.

Ọgbẹni Olawale ni eto tí gomina Adeleke la silẹ ni pe ki onikaluku òṣìṣẹ́ feyinti pada si ìjọba Ìbílẹ̀ wọn láti ṣe ayẹwo iwe wọn.

Bákan náà ní Gomina Ademola Adeleke ti yan àwọn igbimọ kan láti se abewo si awọn to subu lu lẹ níbi ayẹwo náà.