Ìdí tí Akeredolu fi ń ṣisẹ́ láti ìlú Ibadan dípò Akure rèé - Olùbádámọ́ràn ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rotimi Akeredolu
Olubadamọran fun Gomina Ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lori ọrọ isẹ akanse, Doyin Odebowale ni Gomina ko sisẹ lati olu ilu ipinlẹ naa nitori kudiẹkudiẹ to jẹ mọ ibi ti yoo de si.
Akeredolu ni ko ti pada si ipinlẹ Ondo lati igba to pada lati irinajo itọju to lọ ní oke okun.
Ilu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo ni Akeredolu tí n pasẹ ti eyi ko si dun mọ ẹgbẹ alatako ninu ti wọn si n se ìwọde pe ki gomina pada si ipinlẹ naa.
Odebowale lasiko to n sọrọ lori eto momaworan Channels TV salaye pe pẹlu bi ìlera Gomina ṣe wa bayi, o ni nilo ibudo to yanranti lati se isẹ rẹ.
"Aketi de pada ninu oṣu kẹsan an, ni bi to n gbe, ile Aarẹ ti wọn kọ lasiko Aarẹ Olusegun Obasanjo jẹ oni yara meji.
"Ni bayi to ti de, ko le lo ile naa mọ. Ọfisi Gomina atijọ, ti ìjọba to kogba wọle kọ ti di ọfisi fun ileeṣẹ ODIPA.
"Fun idi eyi, Gomina ti n gbe ni ile oni yara meji lati bi ọdun mẹfa sugbọn ìlera rẹ bayi ko gba laye. Yoo nilo gbogbo nnkan to yẹ lati le ṣe itọju ara rẹ. Nitori rẹ ni a fi n kọ ibo miiran fun ti ko si ni pẹ parí."
Odebowale ni o ya oun lẹnu bi awọn kan ṣe n pariwo pe awọn fẹ rí gomina nitori nnkan lọ bo ṣe yẹ ko lọ pẹlu bi ko se si gomina nipinlẹ Ondo.
"Nigba ti wọn ni awọn fẹ rí Aketi, ṣe wọn fẹ rí nibi to ti n gbe apo simẹnti ni. Owo awọn osisẹ lo ti di san, Aketi n bọwọ lu ofin lati gba to ti de pada "












