Wo àwọn fààbú méje tí wọ́n máa ń sọ nípa àwọn obìnrin tí kò rí nǹkan oṣù wọn mọ́

Agbalagba obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹwàá ọdọọdún ni àyájọ́ àwọn obìnrin tí kò rí nǹkan oṣù wọn mọ́ ní àgbáyé.

Ọjọ́ yìí ni wọ́n yà sọ́tọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa àwọn ìlàkàkà tí àwọn obìnrin tó ti wà ní ìpele yìí ń kojú.

Káàkiri àgbàyé, iye àwọn obìnrin tí kò ṣe nǹkan oṣù mọ́ ń pọ̀ sí bí ẹ̀mí àwọn ṣe ń gùn si.

Ní ọdún 2021, àwọn obìnrin tí ọjọ́ orí wọn ti lé ní àádọ́ta ọdún kó ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n àwọn obìnrin tó wà láyé.

Èyí ló jẹ́ àlékún sí ìdá méjìlélógún tó jẹ́ ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe sọ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan àdámọ́ ni fún àwọn obìnrin láti má rìí nǹkan oṣù wọn mọ́ tí ó bá ti tó àsìkò kan síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò mọ́ àgbọ́yé bí ó ṣe máa ń rí lára obìnrin gan-an.

Ọ̀pọ̀ àwọn fààbú ni àwọn èèyàn máa ń gbé kiri káàkiri àgbàyé nípa àìrí nǹkan oṣù mọ́ èyí tí a ṣe àkójọ méje nínú àti ohun tó jẹ́ òótọ́ rẹ̀ gan.

Àwọn náà nìyí:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bákan náà ni àìrí nǹkan oṣù mọ́ máa ń rí lára gbogbo obìnrin

Ìrírí àwọn obìnrin nípa àyípadà tó máa ń wáyé nínú ara wọn máa ń yàtọ̀ síra látara irú ìgbésì ayé tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń gbé.

Ìgbà àti irú àyípadà tó máa wáyé lára àwọn obìnrin máa yàtọ̀ nítorí àwọn ìdí kan sí òmíràn.

Lẹ́yìn àádọ́ta ọdún ni àwọn obìnrin kìí rí nǹkan oṣù wọn mọ́

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ obìnrin ni kìí rí nǹkan oṣù wọn mọ́ tí wọ́n bá ti pé ọdún mọ́kànléláàdọ́ta, àìrí nǹkan oṣù mọ́ lè bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí obìnrin bá ti pé ogójì ọdún sí ọgọ́tà ọdún – èyí tó máa ń yàtọ̀ láti ẹ̀yà kan sí òmíràn.

Dandan ni fún obìnrin láti sanra lẹ́yìn tí wọ́n kò bá rí nǹkan oṣù mọ́

Àìrí nǹkan oṣù mọ́ kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú bí ènìyàn ṣe lè sanra tàbí pẹ́lẹ́ńgẹ́ sí. Àwọn dókítà máa ń gba àwọn èèyàn lámọ̀ràn láti máa ṣe eré ìdárayá ní gbogbo ìgbà kí wọ́n sì máa jẹ oúnjẹ tó dára láti wà ní ìlera pípé.

Ara gbígbóná jẹ́ àìsàn tó máa ń ṣe àwọn obìnrin tí kò bá rí nǹkan oṣù mọ́

Lóòótọ́ ni ará gbígbónà máa ń dàmú ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí kò bá rí nǹkan oṣù wọn mọ́ àmọ́ kìí ṣe gbogbo àwọn obìnrin ni èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀ fún.

Bákan náà ló máa ń wáyé fún ọdún méjì àkọ́kọ́ fún ọ̀pọ̀ obìnrin, tó ìwádìí sì fi múlẹ̀ pé ó máa ń wáyé fún ọdún méje àkọ́kọ́ fún ìdá ọgọ́ta àwọn obìnrin.

Àìrí nǹkan oṣù máa ń pa kí ìbálòpọ̀ máa wu obìnrin ṣe

Ìrònú, kí ojú ara máa gbẹ ní gbogbo ìgbà lé ṣokùnfà kí ìbálòpọ̀ má wu ènìyàn ṣe àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ìlera àti àtìlẹ́yìn ọkọ, àwọn obìnrin yìí tún lè ní ìbálòpọ̀ dáradára.

Àìrí nǹkan oṣù mọ́ máa ń fa ìrònú, àyà jíjá àti kí obìnrin máa dá dì

Àìrí nǹkan oṣù mọ́ kìí fa ìrònú àmọ́ tí èèyàn kò bá rí oorun sùn bó ṣe yẹ tó máa ń sábà wáyé fún àwọn obìnrin tí kò bá rí nǹkan oṣù wọn mọ́ tó sì lè fa kí wọ́n máa kanra àti kí wọ́n máa dádì.

Ṣíṣe ìtọ́jú hòmóònù le fa àìlera

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe ìtọ́jú hòmóònù le pọnkún bí ènìyàn ṣe le ní àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn bẹ́ẹ̀ náà ló lè mú àdínkù bá àìsàn ọkàn àti àwọn ẹ̀yà ara tó máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ kiri.

Ìwádìí ti ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn àǹfàní tó wà nínú rẹ̀ pọ̀ ju aburú rẹ̀ lọ pàápàá fún àwọn obìnrin tí ọjọ́ orí wọn bá dín ní ọgọ́ta ọdún.

Awran ọkọ ati iyawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kí ní àìrí nǹkan oṣù mọ́?

Àìrí nǹkan oṣù mọ́ máa ń wáyé látàrí àyípadà tó máa ń bá àwọn ẹ̀yà ara ìbálòpọ̀ obìnrin bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà si. Ẹ̀yà ara tó máa ń pèsè ẹyin ní oṣooṣù kò ní pèsè rẹ̀ mọ́.

Láàárín ọdún mọárùndínláàdọ́ta sí ọdún márùndínlọ́gọ́ta ni àìrí nǹkan oṣù mọ́ máa ń wáyé ṣùgbọ́n ó lè bẹ̀rẹ̀ síwájú jù bẹ́ẹ̀ lọ fún ẹlòmíràn.

Tí obìnrin kò bá ti rí nǹkan oṣù mọ́ odidi ọdún kan gbáko láì sí ìdí kan pàtó, ó túmọ̀ sí pé obìnrin kò lè bímọ mọ́ nìyẹn.

Kìí sábà dédé wáyé, ó máa ń tó ọdún méje kí ó tó kásẹ̀ tán lára àwọn obpinrin kan, tó sì máa ń gbà tó ọdún mẹ́rìnlá fún àwọn ẹlòmíràn.

Ipele mẹ́ta ni àìrí nǹkan oṣù mọ́ máa ń gbà wáyé:

Ipele àkọ́kọ́ ni ìgbáradì fún àìrí nǹkan oṣù mọ́ tó máa ń wáyé fún àwọn obìnrin tí ọjọ́ orí wọn ti ń wọ ogójì ọdún lọ sí ìbẹ̀rẹ̀ ogójì ọdún.

Lásìkò yìí, obìnrin ṣì máa ma rí nǹkan oṣù rẹ̀ dédé àmọ́ bí ó ṣe ń wà máa yàtọ̀ sí bí ó ṣe máa ń rì tẹ́lẹ̀.

Ipele kejì ni ìgbà tí obìnrin kò ní lè lóyún mọ́. Lásìkò yìí nǹkan oṣù yóò máa wá ségesège, tí kò ní wá ní àwọn oṣù kan tàbí kí ó fi ọjọ́ díẹ̀ wá nínú oṣù kan.

Ipele tó kẹ́yìn ni ìgbà tí obìnrin kò bá ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ mọ́ fún odidi ọdún kan gbáko, tí èyí sì túms sí pé kò lè rí nǹkan oṣù mọ́ títí láéláé.

Awran obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹ́gẹ́ bí àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) ṣe sọ, àwọn àmì àpẹẹrẹ méjìdínláàdọ́ta ló máa ń farahàn lára ẹni tí kò bá rí nǹkan oṣù mọ́.

Lára àwọn èyí tó wọ́pọ̀ ni:

  • Ara gbígbóná àti lílàágùn ní alaalẹ́
  • Kí ojú ara máa gbẹ, kí ojú ara máa dun obìnrin lásìkò ìbálòpọ̀
  • Kí obìnrin má rìí oorun sùn lásìkò
  • Kí àyà máa já, ìrònú àti dídádì
  • Kí egungun má le bíi ti àtẹ̀yìnwá

Àwọn obìnrin míì ní àwọn kìí rántí nǹkan dada mọ́ àti kí gbogbo igun ara máa dun àwọn.

Bákan náà ni àwọn obìnrin mìíràn ní àwọn kò kojú àwọn àìlera yìí àmọ́ ọ̀pọ̀ ló rí àwọn àmì yìí.