''Àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba gbọ́dọ̀ gbé nìyí láti mú àdínkù bá ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ Ajé ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni àjọ tó ń rí sí ètò òǹkà nǹkan ní Nàìjíríà ìyẹn National Bureau of Statistics, NBS gbé ìròyìn jáde nípa bí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ṣe tún ti peléke si.
NBS ní ọ̀wọ́n gógó Nàìjíríà tún ti lé kún sí ìdá 26.72 nínú oṣù Kẹsàn-án k;urò ní ìdá 25.8 tó jẹ́ nínú oṣù Kẹjọ.
Wọ́n ní àwọn oúnjẹ tó gbówó lórí tó ṣokùnfà àlékún náà ni òróró, búrẹ́dì, òdùnkún, iṣu, ẹja, èso, ẹran, ẹ̀fọ́, mílìkì, ẹyin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Láti ìgbà tí ìjọba Nàìjíríà ti yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù nínú oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni gbogbo àwọn nǹkan ti gbówó lórí.
Kí ni àwọn nǹkan tó ń ṣokùnfà bí oúnjẹ ṣe ń gbówó lórí ní gbogbo ìgbà?
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àtẹ̀jáde NBS, onímọ̀ lẹ́ka ẹ̀kọ́ ètò ọrọ̀ ajé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìpínlẹ̀ Kwara, KWASU, Dókítà Felix Gbenga Olaifa ní kìí ṣe ohun tó burú tí iye owó ọjà bá lọ sókè àmọ́ ìgbéléwọ̀n rẹ̀ gbọdọ̀ wá ní ìbámu pẹ̀lú iye tó ń wọlé fún àwọn ènìyàn.
Olaifa ní bí owó àwọn oúnjẹ bá ṣe ń lọ sókè ní ipele bó ṣe yẹ kó dé tó sì jẹ́ pé tó bá ti kọjá bẹ́ẹ̀ nǹkan kò ní rọgbọ fún àwọn ènìyàn.
Ó wòye pé tí a bá wo bí àwọn ọjà ṣe rí ní ogún ọdún sẹ́yìn sí àsìkò tí a wà yìí, bí àwọn oúnjẹ ṣe ń gbówó lórí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú iye tó ń wọlé sí àpò wọn.
Kíkó ọjà àti oúnjẹ wọlé láti ilẹ̀ òkèrè
Ó ṣàlàyé pé lára àwọn nǹkan tó ń ṣokùnfà ọ̀wọ́n gógó ni bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí à ń lò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló jẹ́ pé láti ilẹ̀ òkèrè ni a ti ń kó wọn wọ orílẹ̀ èdè yìí.
Onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé náà ní owó ilẹ̀ òkèrè dọ́là tó ti lọ̀ sókè sí owó Nàìjíríà tí wọ́n fi ń kó àwọn ọjà yìí wọ orílẹ̀ èdè yìí ni ipa tó lágbára lórí iye tí wọ́n máa ta àwọn ọjà náà nígbà tó bá wọ ilẹ̀ yìí.
Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé bí owó dọ́là bá ṣe ń lọ sókè si ni yóò máa ṣe àkóbá fún àwọn oúnjẹ àti àwọn ọjà tí wọ́n bá ń kó wọlé láti àwọn ilẹ̀ òkèrè sí.
Olaifa ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn oúnjẹ tí NBS ní ọ̀wọ́n gógó bá iye wọn yìí ló jẹ́ àwọn nǹkan tí à ń pèsè ní Nàìjíríà, àwọn èròjà tí a fi ń pèsè wọn ló jẹ́ pé láti òkè òkun ni wọ́n ti ń kówọn wá.
“Tí a bá wo búrẹ́dì, wheat ni à ń lò jù láti fi ṣe búrẹ́dì ní Nàìjíríà, ìgbà kàn wà tí wọ́n gbèrò láti máa lo ẹ̀gẹ́ àmọ́ ètò náà kò kẹ́sẹ járí.
“Tí a bá wo wheat, à ń ko wọlé láti ilẹ̀ òkèrè ni, dọ́là sì ti ṣe àkóbá fún-un bẹ́yẹn, ogun tó ń lọ ní Ukraine náà kò jẹ́ kí wheat pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́.
“Oúnjẹ tí àwọn àgbẹ̀ fi ń bọ́ àwọn adìyẹ tó ń yé ẹyin ni a máa ń kó wọlé láti òkè òkun tí dọ́là sì ní ipa lórí iye rẹ̀ nítorí náà ni ẹyin fi gbówó lórí.”
Ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí ìjọba yọ
Olaifa tún fi kun pé ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù ti ìjọba kó ipa tó pọ̀ lórí bí ọ̀wọ́n gógó ṣe bá oúnjẹ ní Nàìjíríà.
Ó ní owó tí àwọn ọlọ́jà fi ń ra epo sọ́kọ̀ ti san fún ọlọ́kọ̀ láti báwọn gbé ọjà wọn láti ibi tí wọ́n rà wan d’ibi tí wọ́n máa ti tà á ló ti gbówó lórí kọjá bó ṣe yẹ.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ọlọ́jà náà máa ṣí owó tí wọ́n fi wọ ọkọ̀ lórí iye tí wọ́n máa ta ọjà wọn náà ni.
Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ tó ń fi ojoojúmọ́ wáyé?
Olaifa ṣàlàyé pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mú àdínkù bá bí wọ́n ṣe ń kó ọjà wọlé láti ilẹ̀ òkèrè tí orílẹ̀ èdè yóò bá bọ́ lọ́wọ́ ọ̀wọ́n gógó tó ń ba fínra.
Ó ní Nàìjíríà pọkún ètò ọ̀gbìn rẹ̀ nípa ríran àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ láti máa pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu tí yóò tó àwọn ènìyàn jẹ, tí yóò sì mú àdínkù bá iye ọjà tí à ń kó wọlé láti ilẹ̀ òkèrè.
“Ìjọba gbọ́dọ̀ ran àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ nípa pípèsè ajílẹ̀ àtàwọn nǹkan mìíràn tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ oko wọn.
Bákan náà ló ní ìjọba nílò láti tètè gbé ìgbésẹ̀ kí wọ́n kó àwọn ọkọ̀ tí kò lo epo bẹntiróòlù wọlé ní kíákíá gẹ́gẹ́ bí wan ṣe ṣèlérí lójúnà àti mú àdínkù bá owó tí àwọn èèyàn ń ná lórí ọkọ̀.
Ó tún ní àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nílò láti kó ara wọn ní ìjánu láti ri dájú pé wọ́n ń ṣàmúlò àwọn nǹkan tí à ń pèsè ní orílẹ̀ èdè yìí.
Onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé náà ní àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò láti yí èrò wọn padà lórí ìhà tí wọ́n ń kọ sí ètò ìjọba kó lè ran àwọn ará ìlú lọ́wọ́.
Ó ní bí ìṣèjọba Muhammadu Buhari ṣe gbé ìgbésẹ̀ láti ti ẹnu ibodè Nàijíríà pa ní àwọn àsìkò láti fi pọnkú pípésè oúnjẹ lábẹ̀lé kò ba ní ipa tó lóòrìn lórí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà tó bá jẹ́ pé àwọn ará ìlú náà tẹ̀lé bó ṣe tọ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
PDP, LP bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba bí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ṣe tún peléke síi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP àti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC lórí bí àlékún ṣe bá ọ̀wọ́n gógó tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àjọ tó ń mójútó òǹkà Nàìjíríà ìyẹn National Bureau of Statistics, NBS gbé ìròyìn jáde lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kẹwàá pé bí owó àwọn oúnjẹ ṣe lékún ti sọ ọ̀wọ́n gógó ní Nàìjíríà di ìdá 26.72.
Iléeṣẹ́ ààrẹ àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC kọ̀ láti sọ ohunkóhun lórí bí àwọn ẹgbẹ́ alátakò ṣe ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí wọn yìí.
Àwọn oúnjẹ tí NBS ní wọ́n gbówó lórí ni òróró, búrẹ́dì, iṣu, ẹja, èso, ẹran, mílíkì, ẹyin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àjọ NBS nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta ní láti ìdá 25.8 tí àlékún náà jẹ́ nínú oṣù Kẹjọ ló ti fò bọ́ sí 26.72 nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023.
Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní bí àwọn oúnjẹ ṣe gbówó lórí yìí ṣàfihàn pé ìṣèjọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu kò lè so èso rere fún orílẹ̀ èdè yìí.
Bákan náà ni olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ní oúnjẹ nii ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń ná owó wọn lé lórí àti pé kò tún ní tó nígbà mìíràn.
APC, Tinubu kò gbáradì fún ìṣèjọba - PDP
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Bola Tinubu àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò ní ìmọ̀ kankan nípa nǹkan tó ń jẹ́ ìṣèjọba.
Agbẹnusọ PDP, Debo Ologunagba nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìjábọ̀ NBS ti ṣàfihàn pé Tinubu àti APC kò gbáradì fún ìṣèjọba pé kí wọ́n ṣà dé ipò lásán ló wà lórí wọn.
Ologunagba ni kò ya àwọn lẹ́nu pé gbogbo nǹkan rí báyìí àti pé ìròyìn náà fìdí ohun tí àwọn ti ń sọ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà múlẹ̀ nípa ìjọba tó wà lóde.
“Nígbà tí ọ̀wọ́n gógó ń bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí APC gba ìjọba lọ́dún 2015, a sọ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà pé nǹkan ma túnbọ̀ bàjẹ́ si.''
“Gẹ́gẹ́ bí ìṣèjọba Muhammadu Buhari, ìṣèjọba yìí tún ti mú àlékún bá àwọn ènìyàn tó ń gbé nínú ìṣẹ́ àti òṣì.”
Ó fi kun pé tí àwọn ènìyàn bá ṣe àgbéyẹ̀wò ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń ṣèjọba, ètò ọrọ̀ ajé jẹ́ ohun tí wọ́n ṣe àmójútó rẹ̀ dáadáa ju báyìí lọ.
Ó ní àpò ìrẹsì tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà lásìkò tí PDP wà nípò ìṣèjọba Nàìjíríà ti lé ní ẹgbẹ́rùn lọ́nà ogójì náírà lásìkò yìí tí owó òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ kò sì kúrò ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà.
Agbẹnusọ PDP náà ní ó dá òun lójú pé Supreme Court yóò dá ẹjọ́ tí àwọn ń pè tako Tinubu bí ó ṣe yẹ tí àwọn yóò sì gba ipò náà padà.
Ó ní ìdẹ̀kùn ń bọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà pé kí wọ́n má mikàn.
Ìjàbọ́ NBS ti ṣàfihàn ìṣèjọba Tinubu – LP, Obi
Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ni bí ọ̀wọ́n gógó ṣe ń bá àwọn ọjà ti ṣàfihàn bí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ṣe ń bàjẹ́ si ojoojúmọ́ lọ́wọ́ ìjọba tó wà lóde.
Agbẹnusọ Labour Party, Obiora Ifoh ní Tinubu, láti ìgbà tó ti gba ọ̀pá àṣẹ kò yan àwọn tó lè mú àyípadà gidi bá Nàìjíríà, pé ó kàn ń yan àwọn tó rí sípò tó ṣe kókó ni.
Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú náà, Peter Obi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí X rẹ̀ ní oúnjẹ jíjẹ ti jẹ́ ìpèníjà fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn bí ó ṣe jẹ́ pé orí oúnjẹ ni àwọn ènìyàn ń ná gbogbo owó tí wọ́n ń pa wọlé sí.
Ó wá rọ ìjọba láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lójúnà àti gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí lọ́wọ́ ìṣẹ́ àti ìyà.
Ó fi kun pé ìjọba gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti pọkún ètò ọ̀gbìn, kí oúnjẹ lè pọ̀ yanturu ní orilẹ̀ èdè yìí àti pé tí wọ́n bá ṣe àmúlò àwọn ilẹ̀ tó wà ní ẹkpun àríwá dáadáa, yóò pèsè owó fún Nàìjíríà ju epo rọ̀bì lọ.














