Pọ̀pọ̀ṣìnṣì ọdún gbé ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ lórí, àjọ aṣèwádí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà, NBS ní ọwọ́jà ọrọ́ ajé ti wálẹ̀

Awọn ọmọ Naijiria n lagun wahala ọwọngogo ounjẹ kọja bayii lọja bi o tilẹ jẹ pe iwadi n fihan pe ọwọja bi ọrọ aje ṣe le sii wa silẹ diẹ losu kọkanla
Ajọ to n sewadi ijinlẹ nipa ọrọ aje ni Naijiria, NBS kede ninu abajade iwadi rẹ lori ọwọngogo ọrọ aje fun ọdun 2021 ṣalaye pe bi ọrọ aje dẹrun diẹ sii fun osu keje ni ṣisẹ n tẹle pẹlu bi ọrọ aje ṣe walẹ lati ida marundinlogun ati mẹjọ o le diẹ ninu ọgọrun loṣu kẹwaa si ida marundinlogun ati mẹrin o le diẹ ninu ọgọrun loṣu kọkanla.
Eyi ṣe afihan ida irọrun onida meji o le meje ati diẹ ninu ọgọrun (2.77%) lati oṣu kẹta ti ọwọngogo ọrọ aje ti gbẹnu soke julọ pẹlu ida mejidinlogun o le ẹyọkan ninu ọgọrun, (18.17 %).
Ninu iwe abajade iwadi nipa ọja rira ati tita ( Consumer Price Index report) fun oṣu kọkanla ni ajo NBS ti gbe eyi jade.
Lara awọn ounjẹ ti wọn yan fun iwadii naa, ko si eyikeyi ninu wọn ti iye ti wọn n taa dinku si iye ti wọn ta wọn losu kẹwaa. Koda orilẹede Naijiria wa lara awọn orilẹede ti ọwọngogo ọja ti n waye julọ lagbaye gẹgẹbi ileeṣẹ aṣewadii Statista ṣe gbe e sita.
Bakan naa ni iwadii ajo aṣewadii ijinlẹ nipa ọrọ aje ni Naijiria NBS naa tun ṣalaye pe ọwọngogo ounjẹ tun rubọ gbẹnu soke sii loṣu kọkanla ni pẹlu ida mẹtadinlogun o le meji ati diẹ ninu ọgọrun, (17.21%) ti a ba fi we bo ṣe ri ni oṣu kan naa lọdun to kọja.
Amọsa, Banki agbaye ti woye pe ohun to n ṣokunfa ọwọngogo lorilẹede Naijiria fẹ yatọ si awọn ti ilẹ miran kaakiri agbaye.
Ninu abajade iwadi tuntun kan to ṣẹṣẹ gbe jade laipẹ yii, O ni ọwọngogo nnkan ṣeeṣe ko ran miliọnu mẹfa o din diẹ eeyan lọ soko oṣi ati iṣẹ laipẹ.
Ninu ọro tawọn onisowo ounjẹ kọọkan sọ lori rẹ, gegele lawọn owo ounjẹ ṣi gbẹnu soke lọja ti ọrọ ati ra ounjẹ di ogun fun ọpọ bayii, paapaa ti ọdun n sunmọ etile.
Gẹgẹbi awọn kan ninu wọn ṣe sọ, kilo ẹran ti kuro ni ẹgbẹrun meji naira bayii, o ti di ẹgbẹrun mẹta naira.
koda afẹfẹ idana gaasi naa ti di goolu lọja ti ọpọlọpọ si n sọ pe ina eedu lawọn n da nile bayii. Wọn ni ẹgbẹrun mẹta abọ Naira ni apo eedun kan eyi to eọrun diẹ fun awọn lati ra ju ẹgbẹrun mẹwaa naira ti garawa oniwọn kilo mejila 12kg afẹfẹ idana gaasi ti da bayii.

















