Coronavirus in Nigeria: Àjọ NBS ní covid-19 ló fa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní ìpínlẹ̀ Eko, Kano, Rivers àti Abuja

Oríṣun àwòrán, others
Laisi ani ani, ajakalẹ arun coronavirus ti da ọwọngogo ounjẹ silẹ nipinlẹ Eko, Kano, Rivers ati Abuja.
Ajọ National Bureau of Statistics to n ri akọsilẹ ohun to n ṣẹlẹ ní Naijiria lo f'ọrọ naa lede.
Ajọ NBS sọrọ naa ninu iroyin to fi sita lori ipa ti aarun onigbameji ti ni nipinlẹ Kano, Eko, Rivers ati Abuja.
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Àwọn èrò yarí lórí sísan owó àyẹwò covid-19 bí bàálù ilẹ̀ òkèèrè ti ba s'Abuja lẹyìn oṣù márùn ún
- Ẹ wo ààrẹ orílẹ̀-èdè tó ń ṣèdárò Ẹja akóredé tó d'olóògbé
- Àbá àpérò 2014 CONFAB lojútùú sí àtúnṣe ìwé òfin Nàìjíríà- Afenifere sáwọn sẹ́nẹ́tọ̀
Ajọ NBS ni ọwọngogo ounjẹ buru jai lawọn nipinlẹ mẹrin wọnyii, amọ awọn eeyan ipinlẹ Rivers ati Abuja ko tii ri nkan nkan.
Ida mejilelaadọrin ninu ọgọrun idile lawọn ipinlẹ naa lo sọ pe awọn ko ri ọwọ mu lọ sẹnu mọ daadaa.
- Ó yẹ kí Buhari dá owó epo padà sí ₦97 tàbí kó kọ̀wé fipò sílẹ̀ - Àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Ọmọ Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìgbéyàwó yálà àwọn ará ìlú fẹ́ràn ìjọba bàbá rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha Buhari
- Owó lítà epo ní Nàíjíríà ló kéré jùlọ l‘Áfíríkà - Lai Muhammed
- Ìjà ẹgbẹ́ òṣèré TAMPAN àti ANTP ni kò jẹ́ kí wọ́n pe Baba Legba sínú eré mọ́, kó tó kú - Owolabi Ajasa
Atẹjade NBS fihan pe ọrọ aje awọn olugbe ipinlẹ mẹrẹẹrin naa dẹnu kọ lẹ laarin oṣu kẹfa si ekeje.
NBS sọ pe afaimọ ki iyan ma bẹ silẹ ni Naijiria nitori awọn mẹkunnu ti n ke wi pe awọn ko rowo ra ounjẹ mọ.









