Constitution Review: Afenifere rọ àwọn aṣòfin láti lo àbá 2014 CONFAB fún àtúnṣe ìwé òfin Nàìjíríà

Reuben Fasoranti

Oríṣun àwòrán, @ngoamazing2009

Ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba, Afenifere ti rọ ile aṣofin agba l'Abuja lati lo aba to jẹyọ nibi apero CONFAB to waye lọdun 2014 fun atunṣe iwe ofin orile-ede Naijiria.

Ẹgbẹ Afenifere, to duro lori pe atunto orile-ede yii ni ojutu si iṣoro to n koju Naijiria, sọrọ yii lẹyin ipade awọn olori ẹgbẹ naa lọjọ Aje labẹ alaṣẹ Oloye Reuben Fasoranti.

Ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin fi sita, ẹgbẹ Afenifere ni awọn gbawọn aṣofin lamọran yii lẹyin ti wọn ranṣẹ si awọn lati kopa ninu eto atunṣe iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 ti a n lo lọwọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Mọ̀ si nípa oríṣìí ẹ̀ka ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àti ìwúlò wọn

Afenifere ni igbesẹ lati ṣe atunṣe iwe ofin Naijiria ti di ohun ti ijọba n kede lọdun mẹrin mẹrin lai si iyipada kankan to ba ofin ọhun.

Ẹgbẹ Afenifere ni yoo jẹ nkan to buru jai ti ijọba ba tun gunle eto atunṣe iwe ofin Naijiria lasiko yii lai ṣe amulo awọn eleyi to ti waye tẹlẹ.

Afenifere sọ pe titẹle awọn aba to jẹyọ nibi apero CONFAB ọdun 2014 nipa ijọba awaarawa lo le mu ilọsiwaju ba Naijiria.

Afenifere tun bu ẹnu atẹ lu afikun owo ina ati epo bentiroolu ti ijọba kede laipẹ yìí.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun tako igbesẹ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja lati jiroro lori aba ti yoo fun ijọba apapọ lagbara lori alumọọni inu omi kaakiri orile-ede Naijiria.