Obaseki, Ize-Iyamu àti Osagiobare sọ̀rọ̀, ilẹ́ kún lórí ìpinnu kóówá fún ìpínlẹ̀ Edo lórí ìpàdé wá wí tẹnuẹ tí BBC Pidgin ṣe

Awọn mẹta pade lori ọrọ Edo ni BBC Pidgin

Mẹta ninu awon oludije naa ti ọpọ eeyan beere fun ni BBC Pidgin gbe wa sori eto ipade itagbangba wa wi ti ẹnu re ṣugbọn ti a ṣe lai jokoo papọ lojukoroju nitori ajakalẹ arun coronavirus to n ba agbaye finra lasiko yii.

Awọn mẹtẹẹta naa ni Gomina Obaseki to n tukọ ipinlẹ Edo bayii labẹ APC ṣugbọn to ti lọ dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Pasitọ Ize Iyamu to n dije ni APC ati Ọgbẹni Jones Osagiobare ti Helen Oyibo BBC si ṣe atọkun eto naa.

Saaju ni Gomina Obaseki kọkọ yọ ara rẹ kuro ninu ipade naa pe igbakeji oun ni yoo sọrọ lorukọ oun.

O ni Phillip Shaibu ni yoo maa ba eto naa lọ ni eyi to bi oludije ẹgbẹ APC ninu ti Osagie si yari pe oun ko ni jiroro pẹlu igbakeji Obaseki.

Lẹyin ti Obaseki lọ kuro lori eto naa lori ayelujara ni Ize Iyamu ni kii ṣe fun awọn igbakeji ṣugbọn wọn tẹsiwaju.

Nigba to pẹ sii naa ni Obaseki tun wa pada de sori eto naa wa wi tẹnu rẹ.

Obaseki Ize iyamu

Ninu ijiroro naa ni Osagie ti fẹsun kan Obaseki pe ko gbiyanju rara ni ipinlẹ Edo

Bẹẹ ni Obaseki dahun pe oun gba maaki ida marundinlọgọrin ninu ọgọrun un ti a ba gbe iṣẹ oun sori iwọn ni ipinlẹ Edo

Ọpọlọpọ ileri lori eto ẹkọ, eto ọgbin, iṣẹ, eto aabo ni awọn mẹtẹẹta sọrọ le lori lati ṣe fun awọn eeyan ipinlẹ Edo ti koowa ba wọle.

Àkọlé fídíò, Àìríṣẹ́ṣe ló mú àwọn ọ̀dọ̀ fẹ̀mí wọn wéwu

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan ann ọdun yii ni eto idibo ti awọn ara ipinlẹ Edo yoo ti yan eni to wu wọn lati dari wọn sori aleefa.

BBC yoo maa gbe gbogbo bo ba ṣe n lọ wa fun un yin!

Àkọlé fídíò, Nítorí owú jíjẹ, ọkọ Zarka gé imú aya rẹ̀ dànú!