Woman pushing police inspector: Obìnrin kan tó ti Ọ̀gá Ọlọ́pàá lulẹ̀ dèrò ilé ẹjọ́ Badagry

Hakeem Odumosu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Arabinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Favour Anueyiagu ti foju ba ile ẹjọ lori ẹsun pe o fiya jẹ Insipẹkitọ Ọlọpaa lọna aitọ.

Ni ile ẹjọ Majisireeti to wa ni ilu Badagry, ipinlẹ Eko lo ti waye nibi to ti n jẹ́jọ́ ẹsun meji to da lori ifiyajẹni ati dida omi alafia ru.

Ọlupẹjọ, ASP Clement Okuimose sọ fun ile ẹjọ pe olujẹjọ naa ṣẹ awọn ẹṣẹ naa lọjọ kẹj oṣu Kejila ni nkan bii ago mẹwa abọ ninu ọgba ile ẹjọ Majisireeti Badagry ni ilu Eko.

O fi ẹsun kan pe olujẹjọ naa fiya jẹ Insipẹkitọ Modinat Esho ti nọmba rẹ lẹnu iṣẹ ọlọpaa jẹ 234392 ti wọn si pin in si ile ẹjọ Majisireeti kẹta ni Badagry nipa bi o ṣe ti i ṣubu lulẹ lasiko to n ṣe iṣẹ oojọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Mariam Balogun kunlekunle to fi gboorọ jẹka laarin awọn akẹgbẹ rẹ

Okuimose ni olujẹjọ naa fi ara rẹ han ni ọna to lee da alafia ru pẹlu bi o ṣe ti olupẹjọ to jẹ Insipẹkitọ ọlọpaa.

Iroyin ni wọn ti fi panpẹ ofin mu Anueyiagu ni kete to ṣẹlẹ ti wọn si ti gbe e le awọn ọlọpaa lọwọ fun ifiyajẹni to ba tọ si i.

Wọn ni ẹṣẹ naa tako abala ofin 174 ati 168 labẹ ofin ọdun 2015 to ni ṣe pẹlu iwa ọdaran ni ilu Eko.

Amọ ẹni to ṣẹ ẹsẹ yii naa ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adaj ile ẹjọ Majisireeti, Fadahunsi Adefioye gba ko san beeli owo ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira pẹlu oniduro meji.

Adefioye ni awọn oniduro mejeeji ọhun gbudọ jẹ awọn to n gbe ni agbegbe ile ẹjọ naa pẹlu ẹri to fihan pe wọn n san owo ori fun ijọba ipinlẹ Eko.

Adajọ ti wa sun igbẹjọ arabinrin Favour siwaju di ọjọ kejila oṣu Kinni ọdun 2022.