Sex in the station: Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Eko yọ ọ̀gá DPO tó sọ ìbọn ọlọ́pàá nu lẹ́yìn tó gbé obìnrin sùn sí ọ́fíìsì rẹ̀ nípò

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọga ọlọpaa ẹkun Denton Divisional police station lagbegbe Ebutte Metta ni ipinlẹ Eko, CSP Adegoke Atilade ti n koju atubọtan ibọn ilewọ amuṣeiṣẹ rẹ to sọnu lẹyin ohun ti iroyin pe ni orun ibalopọ pẹlu ọrẹbinrin rẹ kan.
Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko fi sita ṣalaye pe kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Hakeem Odumoṣu ti paṣẹ ki wọn gbe e kuro ni ipo DPO ẹkun naa.
Igbesẹ naa n waye lẹyin ti okiki iroyin gbode kan pe ọga ọlọpaa Atilade gbe obinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Jennifer Madueke ni agbesun ni ọfiisi rẹ lẹyin eyi ti ko ri ibọn ilewọ iṣẹ rẹ mọ.
- Ìwádìí ti tú àṣírí àwọn tó yìnbọn sí olùwọ́de EndSARS ní Tollgate l'Eko
- Mo dé ilé alálùfáà àti babaláwo kí n tó rí ọ̀rẹ́bìnrin mi tó jí ìbọn mi gbé nínú ọ́físì mi- DPO
- Ògiri amọ̀ wó pa ènìyàn méjì n'Ibadan
- Àwa ọmọ ìlú Igboho kò gbàbọ̀dè fún Sheikh Gumi o, gbọin-gbọin ni à wà lẹ́yìn Sunday Igboho
- Wo ìdí tí ìwọ́de Yorùbá Nation kò fi ní wáyé mọ́ lónìí nílùú Sunday Igboho
Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ni DPO miran yoo gunlẹ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun naa laipẹ.
Amọṣa, atẹjade naa ko sọ ibi ti wọn n gbe ọga ọlọpaa naa lọ bayii.
Atilade ni iroyin gbe jade pe o gbe arabinrin Jennifer si ahamọ ni ileeṣẹ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni SCID ni Yaba lẹyin to ti kọkọ fi si ahamọ fun ọjọ mẹta ni agọ ọlọpaa Denton, Ebutte Meta nilu Eko.
Iroyin sọ pe ọga ọlọpaa Atilade ati arabinrin Madueke ti fi igba kan ri jẹ ọrẹ korikosun ki iṣẹ to gbe to Atilade kuro nilu Eko ni nnkan bii ọdun meje sẹyin. Awọn mejeeji tẹsiwaju pẹlu ere ifẹ wọn lẹyin ti wọn gbe ọga ọlọpaa naa pada silu Eko laipẹ yii.













