Ènìyàn méjì pàdánù ẹ̀mí wọn níbi tí ògiri amọ̀ ti dà wó nílú Ibadan

Ibudo iwayanrin ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ

Eeyan meji ọtọọtọ ni iroyin ti fi idiẹ mulẹ bayii wi pe wọn padanu ẹmi wọn nibi ti wọn ti n gbẹ iyẹpẹ amọ fun akanṣe iṣẹ ni agbegbe Apata nilu Ibadan.

Iṣẹlẹ laabi naa waye lalẹ Ọjọbọ ni ile nla ikẹrusi kan ti wọn n kọ lọwọ ni tosi ile ẹkọ 'Command Secondary school' to n bẹ ni ijọba ibilẹ Ido nipinlẹ Ọyọ.

Alaye ti ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ ṣe fun akọroyin wa ni pe ojo to rọ lasiko naa lo mu ki ogiri amọ naa ya lulẹ ti o si bo awọn eeyan meji mọle.

O tẹsiwaju wi pe ẹni ti o ni ibudo ti wọn ti n ṣiṣẹ naa, Adebayo Idogbe ti o ṣẹṣẹ de pada lati orilẹede China ati ẹlomii ti o jẹ oṣiṣẹ nileeṣẹ naa lo padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ naa.

Amọ to ya lulẹ lo bo awọn mejeeji mọle, ọkan ninu wọn si gbe ẹmi mi loju ẹsẹ ki o to di pe ẹnikeji jẹ Ọlọrun nipe l'ọwurọ ọjọ Ẹti lẹyin ti wọn gbee digbadigba lọ ile iwosan.

Ibudo iwayanrin ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ

Lasiko ti a ṣe abẹwo si ibi iṣẹlẹ naa, a ko ri oṣiṣẹ oṣiṣẹ kankan nibẹ. Alaye ti awọn ara adugbo ṣe ni pe ijamba naa lo mu ki gbogbo awọn oṣiṣẹ kuro ni agbegbe naa.

Adari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ, Adeleke Ismail ti o fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣe alaye wi pe awọn oṣiṣẹ oun ati ikọ Amọtẹkun sarẹ lọ si ibi iṣẹlẹ pajawiri naa lati doola ẹmi awọn eeyan naa, ṣugbọn igbiyanju wọn ja si pabo.

O parọwa si awọn eeyan to ba fẹ dawọ le iru akanṣe iṣẹ bẹẹ lati gba awọn eeyan to mọ iṣẹ naa daju ki iru iṣẹlẹ bẹẹ ma baa waye mọ.

Àkọlé fídíò, N kò lè ṣe gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin, ṣùgbọ́n n kò mọ̀ títí tí mo fi ṣe ìgbéyàwó

Bakan naa ni iṣẹ iwadii tun fi idi ẹ mulẹ pe ile ikẹrusi nla ti wọn n kọ lọwọ nibi iṣẹlẹ naa lo wa lori ilẹ ti o jinkoto, bẹẹ sini oke nla to jẹ kiki amọ yii ka. Lojiji ni oke amọ naa yẹ lulẹ ti o si bo awọn eeyan to wa labẹ ile naa

mọlẹ.