EndSARS Investigative panel: Ìwádìí ti tú àṣírí pé ọta ìbọn àwọn ológun Nàìjíríà ló ṣọṣẹ́ níbi ìwọ́de EndSARS l'Eko

Ni oṣu kẹwaa ọdun 2021 ni yoo pe ọdun kan gbako ti iṣẹlẹ manigbagbe to waye ni Lekki Tollgate nilu Eko lasiko iwọde EndSARS lọdun 2020 ṣẹlẹ, amọṣa ko jọ bi ẹni pe afẹfẹ iṣẹlẹ naa tii jẹ rodo lọ mu omi tan patapata o.
Ni ọjọ Ẹti ni abọ iwadii lọna ati ṣi aṣọ loju awọn eeyan to wọ aṣọ ologun kọlu awọn oluwọde lọjọ buruku eṣu gbomimu naa jade.
Ileeṣẹ aṣeadi nipa imọ ijinlẹ Forensic ti ijọba gbe iwadi naa fun ti kede pe ọta ibọn ologun lawọn ọta ibọn ti wọn yin lu awọn oluwọde lọjọ naa.
- Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Odunlade Adekola nídìí iṣẹ́ tíàtà sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn pé ó ń bá àwọn lòpọ̀
- ''Ìwọ́de Yorùbá Nation kò ní wáyé mọ́ nílùú Sunday Igboho torí a kò fẹ́ wàhálà''
- Ọkùnrin ẹlẹ́wọ̀n kan wọ gàù lẹ́yìn tó gé kórópọ̀n ẹlẹ́wọn míràn
- Àlàyé ohun tọ́rọ̀ adarí ń dá sílẹ̀ ní ìjọ Synagogue lẹ́yìn ikú TB Joshua rèé
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé l’Amẹrika ní 9/11/2001
- Odunlade Adekola yarí lórí ìròyìn tó ní ó n bá àwọn obìnrin sùn kó tó fi wọ́n sínú fíímù rẹ̀
Aṣoju ileeṣẹ naa ti orukọ rẹ n jẹ Joseph Funshọ ṣalaye niwaju igbimọ oluwadi tijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lati ṣe iwadii awọn aṣemaṣe awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi Ọgbẹni Funshọ ṣe sọ, ọdọ ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni wọn ti ri iforukọsilẹ lori awọn ọta ibọn ti wọn lo lọjọ naa ati pe ileeṣẹ ọmọogun Naijiria lo ni wọn.
"Se ẹ rii, lai deena pẹnu, iyatọ wa laarin awọn ọta ibọn ti ileeṣẹ ologun Naijiria gbe kalẹ niwaju igbimọ yii atawọn aloku ọta ibọn ti o wa niwaju igbimọ yii"
O ni awọn aloku ọta ibọn ti awọn ologun wa fihan niwaju igbimọ naa pe o jẹ tiwọn kii ṣe ikan naa pẹlu ohun ti awọn ba pade nibudo akọsilẹ awọn ologun.
O fi kun peawọn aloku ọta ti awọn ologun wa fihan niwaju igbims oluwadi ọhun kii ṣe eyi ti awọn to n ṣe ọta ṣe fun agba ibọn oni 7.62 X 39mm ti wọn lo nibi iwọde naa.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni oṣu kọkanla ọdun 2020 ni olori ikọ ọmọogun ọwọ kọkanlelọganrin 81 Military Intelligence Brigade, Ọgagun Ahmed Taiwo farahan niwaju igbimọ to n wadi iṣẹlẹ manigbagbe to waye ni Lekki Tollgate nilu Eko atawọn aṣemaṣe awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko to si ni ofifo ọta ti ko ni ẹtu kankan ninu lawọn yin ni agbegbe LekkiTollgate ni ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Bakan naa ni Ọgagun Taiwo tun sọ nibẹ pe ofurufu lawọn ọmọogun to lọ sibẹ lsjọ naa yinbọn si, wọn ko yinbọn lu ẹnikẹni ninu awọn oluwọde #EndSARS lọjọ naa.
ọ wa ṣalaye niwaju awọn ọmọ igbimọ naa lọjọ ọhun pe awọn ofifo ọta ibọn ti oun n sọ yii ko lee ṣe ijamba tabi akoba kankan fun ẹran ara eeyan ati pe to ba jẹ pe ọta ibọn tootọ ni wọn yin ni, ẹyọ kan ṣoṣo ọta ibọn naa lee pa eeyan mẹta lọwọ kan naa.
Ṣaaju eyi ni aileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti kọkọ sẹ kanlẹ pe iroyin ofege ni iroyin to ni awọn lawọn yinbọn lu awọn oluwọde nibẹ, ki o to tun di pe o ṣẹri pada to si yi ohun pada pe lootọ awọn wa nibẹ ṣugbọn ofifo ọta ibọn lawọn yin.













