SCOAN: Lati igba ti TB Joshua ti lọ ni ijọ naa ko ti tẹsiwaju mọ nitori ọrọ ta ni yoo ṣe adari rẹ to n jẹyọ- Ìjọ SCOAN

Wolii TB Joshua

Oríṣun àwòrán, other

Ijọ SCOAN, iyẹn Synagogue ti oludasilẹ rẹ, Wolii TB Joshua jade laye loṣu diẹ sẹyin ti ṣalaye pe nnkan o fi gbẹ rọgbọ lori ọrọ tani yoo ṣe olori ni ijọ naa lẹyin ti ilumọọka wolii naa ti jade laye.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ninu eyi ti wọn ti sọrọ lori idajọ ile ẹjọ to ni ki wọn yan iyawo oloogbe naa gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ ijọ naa leyi ti waye.

Ọpọ lo n beere pe ki lo n ṣẹlẹ bayii ni ile ijọsin Synagogue lẹyin iku oludasilẹ ijọ naa, Oloogbe TB Joshua.

Nibayii, ile ẹjọ giga apapọ nilu Eko ti buwọlu iyansipo iyawo TB Joshua gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ ijọ naa ileejọsin naa.

Onidajọ Tijjani Ringim pa aṣẹ yii lasiko to fi n gbe idajọ kalẹ lori ipẹjọ kan ti awọn ọmọ ijọ naa kan pe lorukọ awọn ọmọ ijọ.

Wọn rọ ile ẹjọ pe koyan iyawo oloogbe TB Joshua gẹgẹ bi ọmọ igbimọ oluṣakoso ijọ naa ni ibamu pẹlu ilana ofin ijọ Synagogue to tọka si iye awọn ọmọ igbimọ ọhun.

Wọn ni ọmọ igbimọ naa ni oludasilẹ ijọ naa nigba aye rẹ.

Ati pe awọn meji to ku gẹgẹ bi ọmọ igbimọ ijọ naa ko laṣẹ labẹ ofin lati gbe igbesẹ kankan nipa ijọ ọhun nitori pe eeyan mẹta lo gbọdọ wa ninu igbimọ.

Nitori pe ko si atako kankan latọdọ awọn ti wọn pe lẹjọ, ni ile ẹjọ ba paṣẹ pe ki orukọ iyawo TB Joshua o wọ igbimọ oluṣakoso ijọ naa leyi ti yoo mu ojuutu ba ọrọ aṣiwaju nile ijọsin naa.

Atẹjade ti ijọ naa fi sita lori idajọ ile ẹjọ ṣalaye pe lati igba ti TB Joshua ti lọ ni ijọ naa ko ti tẹsiwaju mọ nitori ọrọ ta ni yoo ṣe adari rẹ to n jẹyọ.