Yoruba nation rally: Ìwọ́de Yorùbá Nation tẹ̀sìwàjú nílùú Sunday Igboho lọ́jọ́ Sátidé

Iwọde Yoruba Nation yoo gberasọ pada lọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanla oṣu kẹsan ọdun 2021 yii ni ilu Igboho tii ṣe ilu abinibi Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Olayomi Koiki to jẹ amugbalẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba naa lo fọrọ yii lede loju opo Facebook rẹ.
Ohun ti a gbọ ni pe iwọde yii yoo waye lati ṣe atilẹyin fun Igboho to wa ni atimọle lorilẹede Benin Republic.
- Kílódé tí Sheikh Gumi fi ṣe àbẹ̀wò sí Igboho nínú gbogbo ìlú tó wà nílẹ̀ Yorùbá?
- Darandaran tó bá rúfín dída ẹran nígboro l'Ondo rugi oyin- Akeredolu yarí
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko buwọ́lu òfin máfi ẹranjẹko láàrín ìlú àti VAT
- Ìjì tó hú igi ńlá ní ìtẹ́ òkú l'Eko ba ibojì òkú 50 jẹ́, àwọn ẹbí sáré lọ w'òkú wọn
- Wo iye mílíọ̀nù tí Miyetti Allah yóò máa ta màálù kan tí ìpínlẹ̀ Eko bá fòfin de ìdẹranjẹko ní gbangba
- Àwọn jàndùkú agbébọn jí òṣìṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo mẹ́ta lọ
- Odunlade Adekola yarí lórí ìròyìn tó ní ó n bá àwọn obìnrin sùn kó tó fi wọ́n sínú fíímù rẹ̀
Iwọde Yoruba Nation ti waye ni ipinlẹ Ogun, Ondo, Osun, Eko ati ipinlẹ Oyo bakan naa.
Iwọde yii lawọn to n ṣe iwọde fi n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba kuro lara Naijiria.
Awọn eekan lagbo oṣelu kan nilẹ Yoruba ko faramọ ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba
Igboho wa ni atimọle lọwọ lọwọ niluu Cotonou lorilẹede Benin Republic.
Oriṣiiriṣii ẹsun ni wọn fi kan Igboho to fi mọ ẹsun wiwọ orilẹede Benin Republic lọna aitọ.
Koiki ṣalaye pe laago mẹwaa ni iwọde naa yoo waye ati pe gbogbo ọmọ Yoruba agbaye ni agbatẹru eto naa.
Igboho is from Aladikun compound in Modeke, Igboho, Oyo state.












