Ondo Bans Unions’/Associations’ Activities : Ìjọba Ondo bẹ́gilé ẹgbẹ́ ọlọ́jà, ó ní wọ́n ń ni aráàlú lára pẹ̀lú ọ̀wọ́ngógó owó orí ọjà

Aworan awọn ọlọja ni ipinlẹ Ondo

Ijọba ipinlẹ Ondo ti fofinde gbogbo awọn ẹgbẹ ọlọja ni ipinlẹ Ondo pẹlu aṣẹ pe wọn ko gbọdọ paṣẹ lori iye tawọn ọlọja yoo maa ta ọja wọn mọ.

Ijọba ipinlẹ Ondo ni oun gbe igbesẹ naa lati daabo bo awọn to n ra aja ni ipinlẹ naa pẹlu bi ọwọngogo owo ori ọja ṣe n waye tawọn ontaja si n bu owo gọbọi le ọja wọn.

Iwa gbigbe owo gegele le ori awọn sja naa ko yọ awọn to n ta ire oko silẹ pẹlu.

Atẹjade kan ti kọmiṣọna fun eto iroyin, Donald Ojogo fi sita ni bi awọn ọlọja ṣe n fi ara ni araalu nipa obitibiti owo ti wọn n gbe lori ọja n kọ ijsba to wa lode ni ipinlẹ ọhun lominu.