Tọkọtaya tí wọ́n ti wà papọ̀ fún ọdún 59 sọ àṣírí àṣeyọrí ìgbéyàwó wọn

Àkọlé fídíò, Tọkọtaya tí wọ́n ti wà papọ̀ fún ọdún 59 sọ àṣírí àṣeyọrí ìgbéyàwó wọn
Tọkọtaya tí wọ́n ti wà papọ̀ fún ọdún 59 sọ àṣírí àṣeyọrí ìgbéyàwó wọn
Aworan Dominic Ayinde Abioudun Enitan ati iyawo wọn Celilia Enitan

Awọn tọkọtaya kan, baba Dominic Ayinde Abioudun Enitan ati iyawo wọn, mama Cecilia Olabisi Abike Enitan ti sọ aṣiri ohun to mu ki igbeyawo wọn pẹ.

Baba Enitan ni Eleduwa fi ore si igbeyawo awọn eleyii ti wọn ṣe ni ọdun 1964.

Baba Enitan to jẹ ọmọbibi ilu Ilewo ni igbeyawo to maa pẹ pẹ pẹ ni okun to so mọ ọ bii suuru ati awo mojukuro.

''Fun apẹrẹ, ko si bi ẹ ṣe le ṣee ti iyawo o ni bi ọkọ ninu tabi ki ọkọ ko ma ṣe nnkan to maa bi iyawo ninu.

Ṣugbọn awọn nnkan ti emi maa n ṣe ti mo ba ri pe inu n bi mi, mo maa n jade ninu ile ti mo ba n binu.

Mo mọ pe ti mo ba fi maa pada wọle, ko si wahala mọ.

Nitori naa, awọn nnkan to yẹ ki a maa ṣe niyẹn kii ṣe pe ki okun maa ho ruru ki ọsa naa maa ho ruru,'' baba Enitan lo sọ bẹẹ.

Mama Cecilia Enitan ni ti wọn sọ ''lati igba ti a ti ṣe iyawo, mi o kuro ni ile ọkọ mi, mi o si lọsi ile wa pe ki wọn ba wa pari ija.

A o le ṣe ka ma ri ija laarin ara wa, amọ, ẹnikan gbọdọ ni suuru.''