‘Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì tí wọ́n ní kó wá ṣe àyẹ̀wò l’Osun ló ń gbé àpò ìtọ̀ rìn kiri’

Àkọlé fídíò, Osun Pensioners:Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì tó dákú l'Osun bá BBC sọ̀rọ̀
‘Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì tí wọ́n ní kó wá ṣe àyẹ̀wò l’Osun ló ń gbé àpò ìtọ̀ rìn kiri’

Ọgbẹni Yemi Lawal ẹni tó jẹ́ olórí ẹka awọn oṣiṣẹ tofẹyinti laarin ọdun 2011/2012 labẹ ẹgbẹ àwọn òṣìṣẹ́ feyinti l'Osun ni awọn kò gbọ iru rẹ rí lásìkò àwọn ìjọba to kọjá ni ipinlẹ Osun.

Olori igun awọn òṣìṣẹ́ feyinti naa tún ṣàlàyé pé àwọn tí ranse tẹlẹ sì gbogbo òṣìṣẹ́ feyinti pe ki wọn maṣe lọ fun ayẹwo naa.

Ki ni ijọba ipinlẹ Ọṣun sọ?

Awọn oṣiṣẹfẹyinti

Rasheed Olawale tó jẹ́ agbenuso fún Gómìnà Ademola Adeleke sàlàyé pe ko si ẹni to ni ki àwọn òṣìṣẹ́ feyinti wá fún ayẹwo ni àkókò yí rara.

O ni gómìnà Adeleke tí se ìpàdé pọ pẹlu awọn òṣìṣẹ́ feyinti ati awọn alaba sise pọ rẹ lati rí pe iru ìṣẹ̀lẹ̀ náà ko ni waye mọ rara.

Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun naa ṣalaye pe gomina Adeleke ti paṣẹ ki wọn gbe eto naa lọ si awọn ẹka idibo apapọ kankan,