PDP ń pè fún yíyọ Akeredolu nípò gómìnà l’Ondo, APC ní àìríkanṣèkan ló ń da PDP láàmú

Oríṣun àwòrán, X/Arakunrin oluwarotimi akeredolu/bbc
Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo ti kesi ile aṣofin ipinlẹ naa lati bẹrẹ igbesẹ ati yọ gomina ipinlẹ ọun, Oluwarotimi Akeredolu nipo.
Ẹgbẹ oṣelu PDP, ninu atẹjade kan ti alamojuto eto ipolongo ati ibanisọrọ rẹ, Kennedy Peretei, fọwọ si sọ pe Akeredolu lo yẹ ki wọn yọ nipo nitori pe “o tabuku iwe ofin orilẹ ede Naijiria tọdun 1999”.
Peretei ni akoko ti to fun ile aṣofin ipinlẹ naa “lati yọ Akeredolu nipo nitori pe gbogbo aye lo ti mọ pe lati bii oṣu mẹfa ni ko ti si adari ijọba nipinlẹ yii leyi to mu ki iṣejọba o dẹnu kọlẹ.
“Ohun to waa buru ju ni pe, kaka ki awọn amugbalẹgbẹ Akeredolu o ṣọ ootọ ọrọ fun araalu, ẹrẹkẹ eebu ni wọn yọ ti wọn leyi to mu ki awọn araalu o bẹrẹ si nii jọwọ aanu ti wọn ni fun gomina naa.
Àìníṣẹ́ ló n dààmú u PDP, Akeredolu dé tán - APC

Nibayii, ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹkun iwọ-oorun guusu orilẹ ede yii ti fesi si ipe ti ẹgbẹ oselu PDP pe fun yiyọ gomina Oluwarotimi Akeredolu nipo.
Olori ọdọ fun ẹgbẹ APC lẹkun naa, Kolade Lawal, to sọrọ nilu Akure wi pe “airikanṣekan lo n daamu ẹgbẹ PDP ti wọn si n wa gbogbo ọna lati ri i pe araalu o gbagbe awọn patapata lẹyin ọpọ ifidirẹmi ninu eto idibo latọwọ APC”.
“Nitootọ ni araalu lẹtọ lati beere adari wọn leyi ti awọn olugbe ipinlẹ Ondo n ṣe bayi nitori ifẹ ti wọn ni si gomina Akeredolu, amọ ẹgbẹ PDP ti gbe arekereke oṣelu wọ ọrọ naa.
O ni bi Akeredolu ko ṣe si nile ko da nkankan duro ninu eto iṣejọba.
Lati ibẹrẹ oṣu kẹsan an ni Gomina Akeredolu ti pada si Naijiria lẹyin to lo pọlọpọ oṣu loke okun lati gba itọju fun aisan to n ba a finra.















