Ohun tí ojú ẹni tó bá ń yàgbẹ́ síta gbangba ní ìpínlẹ̀ Oyo yóò rí rèé - Ìjọba

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/FACEBOOK

Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti máa fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ níbi tó ti ń yàgbẹ́ sí ojú títì tàbí ìta gbangba.

Bákan náà ni wọ́n ní ìjìyà yìí kò ní yọ àwọn tó máa ń dalẹ̀ àti ìdọ̀tí sí ojú ọ̀nà àti tíì bó ṣe wù wọ́n.

Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà, Ọmọba Dotun Oyelade tó ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà níbi ìpàdé ẹkùn gúúsù ìwọ̀ oorun Nàìjíríà láti fòpin sí yíya ìgbẹ́ sí ìrònà tó wáyé ní Ibadan.

Oyelade ní ìgbésẹ̀ láti máa fìyà jẹ àwọn ènìyàn tó bá lòdì sófin jẹ́ ojúná láti fòpin sí dída ilẹ̀ sí àwọn ibi tí kò yẹ àti yíya ìgbẹ́ sí ibi tí kò tọ́.

Ó fi kun pé ó jẹ́ ọ̀nà láti gbógun ti yíya ìgbẹ́ sí ìta gbangba gẹ́gẹ́ bí èròńgbà ìjọba àpapọ̀ láti fòpin síi ní ọdún 2027.

Ó ní gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti pa á láṣẹ fún iléeṣẹ́ tó ń rí ètò ìdàjọ́ láti ri dájú pé wọ́n gbé ìgbìmọ̀ tí yóò máa ṣe ìdàjọ́ àwọn tó bá ń da ilẹ̀ tàbí ya ìgbẹ́ sí àwọn ibi tí kò yẹ.

Oyelade ní òun gbàgbọ́ pé nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ní fìyà jẹ àwọn tó bá tàpá sófin, àyípadà tó lòòrìn máa wà, tí àwọn ènìyàn yóò sí mú ọ̀rọ̀ ìlera wọn ní òkúnkúndùn.

Ó ní ìjọba Oyo ti ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ UNICEF lórí ètò omi àti ìmọ́tótó (WateR, Sanitation and Hygiene).

Ó tẹ̀síwájú pé tó bá máa gba àwọn láti gbé ọ̀rọ̀ síwájú ilé aṣòfin láti fi òǹtẹ̀ lu ìyà tí wọn yóò máa fí jẹ àwọn tó bá lu òfin, àwọn máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó ní ìgbésẹ̀ yìí máa mú kí ìmọ́tótó ìpínlẹ̀ Oyo lékan si àti pé àwọn ṣe ìpolongo lórí ní gbogbo àwọn ibi tó bá yẹ láti ri dájú pé ènìyàn ní ìmọ̀ nípa rẹ̀.

Bákan náà ló jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ìjọba Oyo yóò túnbọ̀ máa ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú UNICEF láti ri pé àwọn ènìyàn kò máa yàgbẹ́ sí ojú ọ̀nà.

Ṣaájú ni aṣojú UNICEF, Monday Johnson ní àjọ tó ń rí sí òǹkà ní Nàìjíríà, National Bureau of Statisticsm, NBS fìí rẹ̀ múlẹ̀ pé kò dín ní mílíọ̀nù méjìdínláàdọ́ta àwọn ènìyàn ní Nàìjíríà ló ń yàgbẹ́ sí ojú títì.

Johnson ní yíya ìgbẹ́ sí inú igbó, ẹsẹ̀ ọ̀nà, inú odò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ ní Nàìjíríà.

Ó ní inú òun dùn pé ìjọba Oyo ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìwà yìí nítorí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ tó ní àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ jùló ní Nàìjíríà.