Mo fẹ́ kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò DNA f'ọmọ Mohbad níbí méjì ọ̀tọ̀tọ̀ nítorí... - Bàbá Mohbad

Aworan Mohbad

Oríṣun àwòrán, @IAMMOHBAD/INSTAGRAM

Ọgbẹni Joseph Aloba ti i ṣe baba olorin takasufee, Ilerioluwa Oladimeji Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad ti sọ pe oun fẹ ki wọn ayẹwo DNA fun ọmọ ti Mohbad bi ni ọna meji ọtọtọ ki aridaju le wa pe Mohbad lo ni ọmọ naa.

Alagba Aloba sọrọ yii ninu fidio kan to ti lu ori ayelujara pa bayii.

Baba Mohbad ṣalaye pe oun n hu gbọ pe wọn ti ṣe ayẹwo naa, amọ ko si ẹni to kan si oun lori ayẹwo ọhun.

Ọgbẹni Aloba ni ''o ṣa yẹ ki n le wa nibẹ tabi ki n ran aṣoju lọ sibi ti wọn ti fẹ ṣe ayẹwo DNA ọhun.

Idi ti a fi gbọdọ ri aridaju pe Mohbad lo bi ọmọdekunrin yii ni pe a kii gba ọmọ ale ni idile wa tori ọmọ Ekiti ni mi.

Ohun ayọ lo maa jẹ fun mi ti ọmọ yii ba jẹ ọmọ Mohbah ni tootọ tori ọmọ kan ṣoṣo to fi silẹ fun mi niyẹn.

Ọjọ mẹta si ọjọ to d’oloogbe ti mo wa pẹlu rẹ ni o gbe ọmọ naa, Liam le mi lọwọ ti o ṣi n ya fọto awa mejeeji papọ.

Amọ, ti o ba jẹ wi pe Mohbad kọ lo ni Liam, ko ni dara tori lọjọ iwaju Mohbad gan an le maa di ẹbi ru mi.''

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Esi ayẹwo oku Mohbad ti n falẹ ju

Ẹwẹ, Ọgbẹni Aloba tun sọ pe esi ayẹwo oku Mohbad tawọn ọlọpaa ṣe ti falẹ ju ko to jade.

O ni oun ko nifẹ si bi oku ọdọmọkunrin ṣe n falẹ lai ti sin in.

‘’Amọ, ohun to ṣẹlẹ ni pe a o lagbara to ijọba niwọn igba to jẹ pe ohun tawọn ọmọ Naijiria lawọn fẹ niyẹn lori oku Mohbad.

Mo ṣi maa pe ọkan lara awọn ọga ọlọpaa lati beere ohun to n jẹ ki esi ayẹwo oku naa ko maa tii jade.

Mo tun maa beere bo ya a le sin Mohbad bayii niwọn igba ti wọn ti wo gbogbo nkan ti wọn fẹ wo lara oku rẹ tan.

Ai tii sin oku rẹ lo jẹ ki ọpọ eeyan maa sọ pe o n yọ sawọn loju ala.

A ni lati sin oku Mohbad laipẹ,’’ baba Mohbad lo sọ bẹẹ.