Ọkùnrin tó fipá bá wòlíì obìnrin láṣepọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọ gbaga ọlọ́pàá l’Ogun

Aworan aṣafihan ojiji eeyan kan to fẹ fi ipa ba obinrin lo

Oríṣun àwòrán, others

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin, ẹni ogoji ọdun kan, Lekan Sunday, ti wọn fi ẹsun kan pe o f’ipa ba wolii obinrin laṣepọ ninu ṣọọṣi.

Ọsẹ to kọja ni wọn sọ pe Sunday f’ipa ba wolii obinrin naa laṣepọ ninu ṣọọṣi rẹ, to wa ladugbo Ilogbo Adu, Kemta niluu Abẹokuta, ki ọwọ to tẹ ẹ.

Oju orun ni wọn sọ pe iya wolii naa wa nigba ti Sunday fi digun wọ ṣọọṣi naa pẹlu awọn nnkan ija, ki o to fi tiptipa ṣi iya wolii naa laṣọ wo lẹyin to ti dunkooko mọ ọ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe nṣe ni Sunday yọ ọbẹ si obinrin naa, to si fi halẹ mọ ọn wi pe bi ko ba gba nnkan toun wa a ṣe, oun yoo gun un pa.

Iya wolii naa pariwo ibosi ara adugbo titi lai si ẹni to gbọ ariwo rẹ rara.

Ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ

Nigba to n f’idi iroyin ọhun mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla sọ pe iṣẹ birikila ni Sunday n ṣe lagbegbe Kemta.

Odutọla ni wolii naa da Sunday mọ daadaa, bi o tilẹ jẹ wi pe alẹ lo fi lọ ka a mọ ṣọọṣi lati ṣe iṣẹ ibi naa,

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun naa ṣalaye siwaju sii peni kete ti ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ẹ, ni iwadii ti bẹrẹ, ko to di pe awọn f’oju rẹ ba ileẹjọ.