UNILORIN sọ̀rọ̀ lórí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó gbẹ̀mí ara rẹ̀ torí owó tó pàdánù sọ́wọ́ gbájúẹ̀

Oríṣun àwòrán, @IM_SIRMAYOR
Ile ẹkọ fasiti ilu Ilorin, Unilorin, ti sọrọ lori iku akẹkọọ rẹ kan ti iroyin sọ pe o gbẹmi ara rẹ lẹyin ti eeyan kan lu u ni jibiti obitibiti owo loju opo ayelujara.
Akẹkọọ naa, Sanni Hameedat, ni fasiti ọhun fidi rẹ mulẹ pe akẹkọọ awọn nii ṣe ati pe iroyin iku rẹ to jẹ ohun to banilọkanjẹ ti de si eti igbọ awọn.
Ṣaaju ni BBC ti kan si ọgbẹni Akogun lati fidi ọrọ iṣẹlẹ yi to gba oju opo ayelujara mulẹ ṣugbọn to sọ pe awọn ko le sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa ayafi ti iwadii ba waye.
Oun nikan kọ, alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara naa, Ajayi Okasanmi pẹlu sọ pe iroyin yi ko ti deti igbọ ohun nigba ti BBC kan si i.
Ọgbẹni Kunle Akogun to jẹ alakoso ẹka ibaraẹnisọrọ fasiti pada wa fi lede pe ''ọna to buru ni arabinrin yi gba lọ paapa ẹni to ṣe pe o ni anfaani lati di eeyan lọjọ iwaju''
Akogun ṣalaye pe awọn gbọ nipa iku rẹ to waye lẹyin ti idunadura kan to ṣe fori sanpọn.
Ko sọ pato ẹni to baa dowo pọ ti idunadura naa fi fori ṣanpọn tabi iye to jẹ ti arabinrin naa padanu ninu idunadura yi.
O jẹ iyalẹnu fun wa pe akẹkọọ wa lajọṣepọ pẹlu ọrẹkunrin gbajuẹ?
Atẹjade ti Akogun fi sita tẹsiwaju lati sọ pe o ya awọn lẹnu gẹgẹ bi ileekọ to ja fafa nipa kikọ awọn ọmọ lẹkọ ati iwa daa wi pe akẹkọọ awọn yoo ni nkan ṣe pẹlu ọrẹkunrin ti ọwọ rẹ ko mọ debi pe yoo tẹsiwaju lati gbẹmi ara rẹ''
Bẹẹ ni fasiti ọhun fi kun pe awọn fi akoko yi kilọ fawọn akẹkọọ lati yago fawọn ọrẹkọr ki wọn ma baa ko si ọwọ awọn onijibiti.
Ọrọ yi jọ bi ẹni pe o kin iroyin to gbode pe ọrẹkunrin kan ti Hameedat pade loju opo ibaraẹnisọrọ kan lo lu ni jibiti owo to sunmọ miliọnu kan Naira.
Gẹgẹ bi iroyin taa ri ka lọdọ ileeṣẹ iroyin Naijiria nii Punch ati awọn oju opo ayelujara kan, ọrẹkunrin yi parọ fun Hameedat pe oun nilo owo to to miliọnu kan lati fi san owo iṣẹ abẹ fun iya rẹ ti aisan n daa laamu ni.
Owo to wa lọwọ Hameedat gẹgẹ bi a ṣe gbọ lo foju aanu ko fun arakunrin yi to si tun ya owo mii lọwọ awọn oju opo ayanilowo ki owo to nilo baa le pe.
Owo to wa lọwọ Hameedat tẹlẹ jẹ owo ti iya rẹ ko si lọwọ gẹgẹ baa ṣe gbọ.
Itiju ati ibanujẹ ọkan lo mu ki Hameedat gbe majele jẹ
Apa iroyin to niṣe pẹlu ohun ti Hameedat lo lati fi gbẹmi ara rẹ jẹ eleyi taa le fẹsẹ rẹ mulẹ.
Amọ ninu iroyin ti Punch ko jọ, wọn ni awọn to sare gbe Hameedat lọ si ile iwosan lati ile igbe rẹ to wa sọ pe majele ''Sniper'' lo gbe jẹ to si ti bẹ n ke irora ki wọn to gbe lọ si ileewosan ikọṣẹ Fasiti Ilorin.
Nigba ti wọn gbe de ile iwosan lawọn oniṣegun kede pe o ti dero ọrun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti sọ pato ohun to ṣokunfa iku rẹ atipe boya wọn ti mu iroyin iku rẹ wa si eti igbọ wọn.
Lọpọ igba tawọn ọdọ tabi agbalagba mii ni Naijiria ba fọwọ ara wọn gbẹmi ara wọn, majele tabi ipokunso lọna ti wọn maa lo lati fi dagbere faye.
Fasiti naa sọ pe wọn ti sinku Hameedat nilana musulumi ni iṣoju awọn obi rẹ.
Ipele kẹta ni Hameedat wa ti o si n kọ ẹkọ nipa imọ Microbiology ki o to jade laye.












