Wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti 'jápa'

Aworan Helen Paul, Adekunle Gold ati Bukky Wright

Oríṣun àwòrán, Instagram

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe awọn ọmọ Naijiria n rinrin ajo lọ si oke okun ti wọn ba ti ri anfaani kekere kan.

Ọpọ wọn, bi wọn ba n ṣalaye ohun to fa a, wọn a maa sọ pe nitori idojukọ ti wọn n ba pade lorilẹede abinibi wọn ni.

Yatọ si eyi, awọn miiran a maa sọ pe nitori aisi eto aabo to pe ye, aisi iṣẹ gidi, ati bi gbogbo nkan ṣe gbe owo lori, aisi opopona to dara, to fi mọ ina mọnamọna to n ṣe ṣege ṣege, ati awọn nnkan miran lo n jẹ kawọn maa fi ilu silẹ.

Ṣugbọn fun awọn miiran bi wọn ba n ṣalaye idi pataki ti wọn ṣe n kuro ni Naijiria, wọn a maa sọ pe ọna atila, ati ṣe oriire ni awọn n wa lọ.

Lara awọn to tun n jẹ iyalẹnu fun ọpọ awọn ọmọ Naijiria tun ni bi awọn to jẹ gbajugbaja bii onkọrin ati oṣere naa ṣe n fi orileede wọn silẹ lọ si orileede miiran, eyi ti wọn n pe ni ‘Japa’.

Japa yii jẹ ede ti awọn ọmọ Naijiria n lo lati ri ṣapejuwe awọn ti wọn n ba ẹsẹ wọn sọrọ kuro niluu, lati wa atijẹ atimu lọ si orilẹede miiran ti ori n gbe wọn lọ.

BBC Yoruba ti wa a mu diẹ lara awọn ilumọọka oṣere ati olorin ti awọn naa ti japa kuro ni Naijiria lọ si orileede miiran lati lọ tẹdo sibẹ.

Diẹ lara awọn ilumọọka ọmọ Naijiria ti wọn ti fi orilẹede yii silẹ lọ si oke okun ni wọnyii:

Bukky Wright

Aworan Bukky Wright

Oríṣun àwòrán, Bukky Wright/Instagram

A fẹẹ le sọ pe oṣelu lo gbe Bukky Wright kuro nidi iṣẹ tiata, to si pẹlu awọn gbajumọ oṣere tiata ti awọn naa ti ‘japa’ kuro ni Naijiria.

Oniṣowo ati oloṣelu ni Oluwabukola ti ọpọ awọn eeyan mọ si Bukky Wright nidi iṣẹ tiata to fi gbajumọ, ẹni ti wọn bi lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 1967.

Ọdun 1996 ni Bukky Wright darapọ mọ iṣẹ tiata, to si ti kopa ninu fiimu agbelewo loriṣiriṣi ni ti Yoruba ati oloyinbo.

Inu sinima ọlọsẹ-ọsẹ to jẹ ti gbajugbaja ere ori itage Wale Adenuga ti a mọ si Super Story ni Bukky Wright ti di ilumọọka.

Ju gbogbo rẹ lọ, oriṣiriṣi iroyin lo ti jade sita wi pe iya ọlọmọ meji naa ti di ọkan lara awọn oṣiṣẹ ọlọpaa otẹlẹmuyẹ l’Amẹrika, eyi ti a mọ si Information Security Auditor.

Helen Paul

Aworan Helen Paul

Oríṣun àwòrán, Helen Paul/itshelenpaul

Bi wọn ba n sọ nipa awọn obinrin ti wọn n sọ iṣẹ apanilẹrin di irọrun lorileede Naijiria, odu ni Ọmọwẹ Helen Paul, kii ṣe aimọ f’oloko rara.

Helen ti ọpọ mọ si Tatafo pẹlu awọn gbajumọ oṣere Naijiria ti wọn ti kuro ni Naijiria lọ si Amẹrika, bo tilẹ jẹ pe o ṣi n gbe orukọ Naijiria larugẹ kaakiri nipa gbigbe oriṣiriṣi eto ọlọkan-o-j’ọkan kalẹ ni Naijiria ati loke okun.

Bi Tatafo ṣe n ṣiṣẹ apanilẹrin naa lo tun jẹ oṣere tiata, to si tun jẹ onkọrin.

O kẹkọọ gboye ninu ere ori itage ni fasiti ipinlẹ Eko, to si tun gboye Ọmọwe ni fasiti kan nilẹ Amẹrika.

Ọdun 2022 ni wọn kede rẹ gẹgẹ bi oludari ẹka ikẹkọọ amuludun ni fasiti Heart International University to wa ni Amẹrika.

eLDee

Aworan elDee

Oríṣun àwòrán, elDee/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orukọ abisọ rẹ gangan a maa jẹ Lanre Dabiri, eLDee jẹ gbajugbaja olorin takusufee, to si pẹlu awọn olorin akọkọ ti wọn bẹrẹ sii lo adamọdi ede lati fi kọ orin, eyi ti oloyinbo n pe ni ‘RAP’.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun 1977 ni wọn bi Lanre Dabiri ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si eLDee niluu Kaduna.

eLDee wa lara ikọ ẹgbẹ olorin ti wọn da silẹ l’ọdun 1998, eyi ti wọn pe ni Tyrbesmen.

Lara awọn ti wọn si jọ wa ninu ẹgbẹ naa ni KB ati Freestyle, ti wọn jọ n fi adamọdi orin dabira fun awọn ololufẹ wọn.

Awo orin marun-un loun funra rẹ ti da ṣe, ko to di pe o dẹkun orin kikọ l’ọdun 2019, bo tilẹ jẹ pe o sọ funra rẹ wi pe oun ko kabamọ wi pe oun fi iṣẹ orin kikọ silẹ, paapaa bo tun ṣe sọ pe iṣẹ orin kikọ ko fun oun laaye lati gbajumọ ọrọ idile oun.

Bo tilẹ jẹ pe eLDee, ẹni to ti fi Naijiria silẹ lati lọ maa gbe ni Amẹrika loun ti fẹyinti nidi iṣẹ orin kikọ, sibẹ lẹẹ kọọkan, o ṣi maa n fi orin da awọn ololufẹ rẹ laraya lori ikanni ayelujara.

Lara awọn orin to kọ ni ‘Big Boy’, ati ‘Is It Your Money’.

Adekunle Gold and Simi

Aworan Adekunle Gold ati Simi

Oríṣun àwòrán, Adekunle Gold/Instagram

Ọkọ ati iyawo ti wọn nifẹẹ ara wọn daadaa ni Adekunle Gold ati Simisọla.

Laipẹ yii ni awọn naa fi orileede Naijiria silẹ lati lọ maa gbe nilẹ Amẹrika.

Ko pe ti wọn bi akọbi wọn, Adejare ni wọn fi Naijiria silẹ.

Bi wọn si ṣe kuro ni Naijiria yii, wọn ko da awọn ololufẹ wọn lagara, pẹlu bi wọn ṣe n gbe orin ọkan-o-jọkan jade sita fun awọn olulufẹ wọn.

Regina Askia

Aworan Regina Askia

Oríṣun àwòrán, Regina Askia/Instagram

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 1967 ni wọn bi gbajugbaja oṣerebinrin nni, Regina Askia-Williams.

Ilu New York City ni Amẹrika ni Regina Askia o n gbe bayii.

Ṣe bi ori lo mọ iṣẹ aṣela, iṣẹ nọọsi ni Regina yan laayo bayii l'Amẹrika, to si gba iwe ẹri nipa iṣẹ nọọsi ọhun.

Omoni Oboli

Aworan Omoni Oboli

Oríṣun àwòrán, Omoni Oboli/Instagram

Odu ni Omoni Oboli nidi iṣẹ tiata, ẹni to kawe ni ileẹkọ New York Film Academy, to si ti gba oriṣiriiṣi ami ẹyẹ.

Awọn sinima awo ma lee lọ ni Omoni Oboli ti kọ, lara wọn si ni ‘The Figurine (2009)’; ‘Anchor Baby (2010)’; ‘Fatal Imagination’; ‘Being Mrs Elliott’; ‘The First Lady’; ati Wives on Strike (2016).

Yatọ si pe o kopa ninu sinima apanilẹrin ‘Moms at War l’ọdun 2018, oun lo tun dari fiimu naa.

Bo tilẹ jẹ obinrin ọlọmọ mẹta naa ti ko gbogbo idile rẹ lọ orilẹede Canada, o si tun wa si Naijiria lẹẹkọọkan nigba to ba ti ni iṣẹ to ṣe pataki lati ṣe.

Bouqui

Aworan Bouqui

Oríṣun àwòrán, Bouqui/Instagram

Bi wọn ba n darukọ awọn obinrin to sọ iṣẹ orin takasufee aladamọdi kikọ di irọrun, odu ni Bukọla Fọlayan ti wọn bi lọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 1979.

Bi ẹ ba pe e ni Bouqui tabi B.O.U.Q.U.I., ẹni kan ṣoṣo lẹ ṣi n darukọ.

O si gbajumọ daadaa l’ọdun 2007 nigba to gba aami ẹyẹ ti Headies gẹgẹ bi olorin takasufee aladamọdi to peregede julọ ati olorin obinrin to dara julọ l’ọdun naa.

Yatọ si ami ẹyẹ Headies, o tun gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi olorin obinrin to ṣe daadaa julọ l’ọdoun 2007 kan naa.

Orin adakọ rẹ to pe ni ‘Take You Away’ tun gba eyi ti wọn wo julọ lori ayelujara lọdun 2010, to si gba ami ẹyẹ NMVA.

Bi a ṣe n sọrọ, Bouqui ti di ọmọ ilẹ Amẹrika, to si tun ti di oniwaasu nibẹ.

Modenine

Aworan Modenine

Oríṣun àwòrán, Modenine/Instagram

Ọkan pataki lara awọn agba ati alẹnulọrọ nidi iṣẹ lilo adamọdi ede fi kọ orin ti a mọ si ‘RAP’ ni Babatunde Oluṣẹgun Adewale ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Modenine.

Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹfa, ọdun 1975 ni wọn bi Modenine, ọmọ ipinlẹ Ọṣun ni i ṣe to si wa ni ipo kẹta ninu awọn ọmọ ti iya ati baba rẹ bi.

Ki Modenine too pada si United Kingdom ti wọn bii si, o ṣiṣẹ nileeṣẹ redio Rhythm 84.7FM to wa niluu Abuja, gẹgẹ bi agbohunsafẹfẹ.

Gẹgẹ bi onkọrin, o sọ pe Naijiria ko mọ riri orin ati ẹbun rẹ, idi to fi lo di dandan lati kuro lọ si orileede miran.

Lara orin to kọ ni ‘Cry and Show Me Love’.