Bùọ̀dá àdúgbò ni Kamo jẹ́ sí mi, ọjọ́ tá a bẹ̀rẹ̀ àwàdà la ra àṣọ àti koto Nepa - Ozain
Odu ni Kamo ati Ozain lori ayelujara nitori awada ori ayelujara Nepa Boys ti wọn n se.
Ẹrin arintakiti si ni awọn ololufẹ wọn maa n rin lasiko ti wọn ba n se awada loju opo wọn Nepa Boys.
Amọ nigba to ya, a sakiyesi pe awọn mejeeji ko se awada papọ mọ loju opo Nepa Boys.
Ikọọkan wọn si lo da duro loju opo ayelujara wọn lati maa se awada wọn lai se awada papọ mọ bii Nepa Boys.
Idi si ree ti BBC Yoruba fi tọ Hussein Mubarrak Kehinde lọ, ti ọpọ eeyan mọ si Ozain ninu awada ori ayelujara Nepa Boys.

A fẹ mọ idi ti oun ati Kamo fi yapa lati maa se awada papọ ati pe se ija lo de bi?
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ozain ni ko si ija kankan laarin oun ati Kamọ, awọn si maa n sọrọ daadaa.
“Buọda adugbo ni Kamo jẹ si mi, a jọ gbe ni adugbo kan naa tẹlẹ ni, ka tun to pade pada.
Asiko ti wọn pe wa lati kopa ninu sinima kan la tun pada, ti Kamo si daba pe ka bẹrẹ awada Nepa Boys.
Ọjọ ta si fẹ gbe awada akọkọ sita ni a lọ ra asọ ati koto ori ta n lo ninu awada naa.
Bi a si se gbe awada akọkọ sita, lo jẹ itẹwọgba, ti awọn eeyan si fẹran wa.”
Bakan naa ni Ozain sọ pe oun ati Kamo ko ja rara, koda awọn si sọrọ ni bii ọjọ meji sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Nepa Boys
O fikun pe ikọọkan awọn lo ti da wa tẹlẹ, ti awọn si n se awada awọn loju opo ayelujara, ko to di pe awn bẹrẹ ere Nepa Boys.
Ozain wa kede pe oun ti se ọpọlọpọ nnkan, ki oun to di alawada lori ayelujara.
O ni oun maa n sisẹ Taylor, DJ, ti oun si tun kawe.






