EFCC jẹ́wọ́ ìdí tó fi pe Afọbajẹ Oyo méje lórí ẹ̀sùn gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ọmọ oyé tó dupò Alaafin

Aafin Alaafin Oyo

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorileede Naijiria, EFCC sọ pe lootọ lawọn pe awọn afọbajẹ Ilu Oyo kan lati wa dahun ibeere nipa ẹsun ti eeyan kan fi kan wọn.

Ẹsun yi gẹgẹ bi EFCC ṣe sọ ni i ṣe pẹlu gbigba abẹtẹlẹ lati yan Alaafin Oyo tuntun ninu awọn to dije dupo naa.

Agbẹnusọ ajọ naa Dele Oyewale lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC.

O ni ọfisi awọn to wa ni Ibadan lo fi iwe pe awọn kan ninu awọn afọbajẹ Ilu Oyo lati wa dahun ibeere ẹsun ajẹbanu ti olupẹjọ kan fi kan wọn.

''Awọn meje la fi iwe pe, meji ninu wọn si dahun ipe wa ti wọn si ti wi tẹnu wọn''

Dele Oyewale sọ pe ajọ naa ko le darukọ awọn to fi ẹsun kan awọn afọbajẹ yi.

Bẹẹ lo si ni awọn ko tun le darukọ awọn ti awọn fiwe pe ninu awọn afọbajẹ naa.

''Ko si ninu ilana wa lati darukọ wọn. A ko si tun le sọ oludije ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn gba owo lọwọ rẹ''

Alaafin Adeyẹmi to gbesẹ

Ojo ketalelogun, osu kẹrin, ọdun 2022 ni Oba Atanda Olayiwola Adeyemi waja.

O lo ọdun mejilelaadọta lori alefa ko to waja.

Lati igba to ti papoda ni awọn to n dije dupo naa ti n kopa ninu ifọrọwanilẹnuwo lọdọ awọn Oyo Mesi to n ṣeto ẹni ti yoo di Alaafin tuntun.

Mọkandinlaadọrun lawọn to n du ipo yi.

Idile Agunloye ni ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe o yẹ ki oriade naa ti wa gẹgẹ bi iwe kan ti wọn fi sita amọ awọn idile ọlọba mẹsan to ku ti wọ ijọba lọ sile ẹjọ ki wọn baa le fawọn naa lanfaani ati du ipo niwaju awọn afọbajẹ.

Titi di akoko yi, wọn ko ti yanju ẹni ti wọn yoo kede gẹgẹ bi Alaafin tuntun ti Gomina Seyi Makinde si sọ laipẹ yi pe ipo Alaafin kii ṣe fun tita ati pe ẹni ti wọn ba ri pe o n gbero lati fowo ra ipo naa, awọn yoo fa le awọn agbofinro lọwọ.

O ṣeeṣe ki ọrọ Efcc to kesi awọn afọbajẹ yi so mọ nkan ti Gomina sọ tori iwe ti ajọ naa lawọn ri gba da lori ẹsun ajẹbanu ti eeyan kan fi kan awọn afọbajẹ.

Ki lo ṣẹlẹ nigba ti awọn afọbajẹ yi de si ọfisi Efcc?

Agbẹnusọ Efcc to ba BBC sọrọ ko ṣalaye lẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ nigba tawọn afọbajẹ yi de ọfisi wọn amọ o ni awọn meji to yọju ti dahun ibeere ti yoo ṣe awọn lanfaani lati tẹsiwaju iwadii ọrọ.

Ileeṣẹ iroyin Naijiria The Nation jabọ pe ọpọ wakati lawọn afọbajẹ meji to yọju lo ti wọn fi n dahun ibeere.

O fi kun pe awọn agbẹjọro wọn wa ni ikalẹ pẹlu wọn bi wọn ṣe ndahun ibeere ti awọn oṣiṣẹ ajọ yi fi ṣọwọ si wọn.

Awọn afọbajẹ yi ti pada si ile wọn ṣugbọn ko si ẹni to jade lati sọ pato iru ibeere ti wọn beere lọwọ wọn.

Efcc ko sọ bakan naa boya ijiya yoo wa fun awọn afọbaje marun to ku ninu awọn meje ti wọn kọ lati dahun ipe ti ajọ naa fi sọwọ si wọn.