Àwọn 10 pegedé nínú 86 tó sẹ ìfọ́rọ́wánilẹ́nuwò fún ipò Aláàfin

Oríṣun àwòrán, Bode Durojaiye
Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ Ọyọ mesi ti pari ifọrọwanilẹnuwo fun awọn oludije to fẹ du ipo Alaafin Ọyọ, apapọ awọn oludije marundinlaadorin lo wa fun iforowanilenuwo.
Adele Alaafin Ọyọ, Yussuf Akinade Ayoola Layinka 1, Basorun ti Ọyọ, fi idi eyi mulẹ.
O ni pe ninu awon marundinlaadorin omọọba to lẹtọọ si ade naa ti wọn si ti fi ifẹ han lati dije dupo Alaafin, awọn mẹwaa nikan ni o yẹge ninu ifọrọwanilẹnuwo naa.
Kini igbesẹ to ku lẹyin ifọrọwanilẹnuwo yii?
O sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Ọyọ Mesi yoo pade laipẹ lati pinnu lori igbesẹ ti wọn yoo tẹle, eyiti sẹ iwadii lẹnu Ifa.
Basorun Ọyọ ni eni ti o ba bori laarin awọn mẹwaa to sẹku ni yoo jẹ Alaafin Oyo tuntun.
Adele Alaafin nigba ti o n sọrọ lori ẹsun gbigba 200k lọwọ awọn to fife han lati di Alaafin titun.
O ni: gbogbo igbese awọn ko sẹyin ijọba ipinlẹ Ọyọ nitori ijọba ran aṣoju wa sibi ifọrọwanilẹnuwo naa.
Basorun Ọyọ ni Alaga ijọba ibilẹ Atiba láṣọ ju gomina ipinlẹ Ọyọ ninu awon ẹto ifọrọwanilẹnuwo ti awọn ṣe.
Ìdílé 9 nínú ìdílé 11 tó yẹ fún oyè Alaafin ní kí Makinde fòpin sí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwò sípò Alaafin

Oríṣun àwòrán, ALAAFIN OYO /FACEBOOK
Mẹsan an ninu awọn idile ọba mọkanla to wa lati idile Alaafin Atiba ti pe fun Ifagile ifọrọwanilẹnuwo ti n lọ lọwọ fun awọn omo oyemerindinladorun to fe je oye Alaafin Oyo.
Awọn idile naa ni Tella Okitipapa, Adediran Ese Apata, Olanite, Adelabu Baba Ibadan, Adesiyan, Adesokan Baba Idode, Iteade Abidekun, Adeitan ati Tella Agbojulogun.
Wọn ni ikuna ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ṣe ohun to ye ni ti yiyan eni ti o tosi yoo yọrisi wahala labẹ ofin.
Eyi ti o le mu ki wọn yọ ẹnikẹni tọ ba jẹ Alaafin kuro.
Agbenuso fun awon idile torokan Ọmọọba Afolabi Adeshina (lati idile Oba Adeitan) sọ pe o yẹ ki ijọba duro de ipari ẹjọ ni kootu ki wọn to tẹsiwaju pẹlu ilana yiyan Alaafin.

Oríṣun àwòrán, Alaafin oyo/facebook
O ni, leyin iku Oba Lamidi Adeyemi ni ijoba fi iwe ranse si Baba Iyaji ni ojo kesan an, osu kejo, odun 2022.
Pe ki won yan Oba titun ninu idile Agunloye ki o si safihan re fun igbimo Oyo Mesi lai se akiyesi awon idile mesan an to ku.
Adeshina so pe awon idile mesan an to seku fe ki eto yiyan oba titun nilu Oyo je sisi sile fun gbogbo idile to leto si oba jije nilu Oyo
Oba lamidi Adeyemi Alowolodu keta,lo waja lorumọju ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, odun 2022 lẹyin aisan ranpẹ to si lo ọdun mejilelaadọta lori itẹ awọn baba nla rẹ ni ilu Oyo.
Gẹg bi aṣa, lootọ naa si ni, ko sẹni to lee wo o loju pẹlu arifin tori "iku baba yeye, alaṣẹ ekeji ooṣa ni Yoruba n pe e












