Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji
Alaafin Oyo ati Sat Guru Maharaj-ji

Èmi ni ọ̀nà tó ń kọ́ àwọn eèyàn ní Ifá àti bí wọ́n ṣe ń ṣe mọ́tò àti 'Plane' lójú ìran- Sat Guru Maharaj-ji

BBC Yoruba lo ba oludasile ẹsin One Love Foundation, Sat Guru Maharaji-ji lalejo ni ibugbe rẹ ni agbegbe Guru ni ilu Ibadan ni ipinle Oyo, guusu Iwo Oorun Naijiria.

Bola Ige ati Guru

Nibẹ ni Sat Guru Maharaj-ji ti sọrọ nipa iku to pa Alaafin Oba Lamidi Adeyemi, to pa Bola Ige ati Penkelemesi.

O ni pe Iku Baba Yeye gbọdọ pada wa saye ni nitori pe koi tii lo ọjọ to yẹ ko lo tan laye.

Sat Guru sọ pe Alaafin Iku Baba Yeye ko ṣe e pa ṣugbọn ija n bẹ nita ati pe igboro ko fini lọkan balẹ.

O tun sọrọ nipa pataki igba iwaṣẹ ati iṣẹṣe gẹgẹ bii ona abayọ si ija ẹsin.

Sat Guru ni pe laye atijọ awọn arugbo wa maa n le ni ọgọrun un lọjọ ori daadaa.

Ati pe oun n reti abajade ọrọ pẹlu awọn ọmọoba ni.

Sat Guru Maharaj-ji

Ìjà ẹ̀sìn láti ọ̀dọ̀ òyìnbó kò yẹ kó pín wa ní Naàijíríà-Sat Guru

Bakan naa ni Sat Guru ni ọwọ́ ikú tó pa Bola Ige náà kò mọ́.