Ogun Cultist: Ọwọ́ tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìtura, wo nǹkan tí ọlọ́pàá ká mọ lọ́wọ́

Afurasí

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ọwọ palaba ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti segi ni Ogun nibi lẹyin ti ọwọ awọn agbofinro tẹ.

Afurasi naa Christian Peter la gbọ pe ọwọ tẹ ni ọjọ Isegun tii se ọjọ Kẹwaa, osu Karun un, ọdun yi.

Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, fi sita,o ni o ti to ọjọ mẹtaa kan ti wọn ti n wa afurasi yi ki awọn ọlọpaa agọ to wa ni Mowe to wa pada ri mu.

A gbọ pe ni ile itura kan to wa ni adugbo Olororo, Mowe ni o ti ko si awọn ọlọpaa lọwọ.

Gẹgẹ bi wọn se wi, kete to ri awọn ọlọpaa lo gbiyanju lati fẹsẹ fẹ sugbọn awọn agbofinro ri mu ko to ribi sa lọ.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Wọn ba igbanu kan lọwọ rẹ.

Nigba ti wọn yẹ inu rẹ wo, wọn ri pe ibọn agbelẹrọ kan pẹlu ọta mẹrin lo wa ninu rẹ.

Awọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe o wa lara awọn ọdaran to n ka awọn ara adugbo laya soke ni agbegbe Mowe/Ofada lẹnu ọjọ mẹta yi..

Afurasí

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command

Ẹwẹ, ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Kọmisana Lanre Bankole ti pasẹ ki wọn gbe afurasi yi lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ to n se iwadii iwa ọdaran fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Alaboyun

Oríṣun àwòrán, @NDLEA

Kini o tun ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ọwọ́ pálábá NDLEA tẹ aláboyún méjì, 'barber' kan àti àwọn afurasí mí tó gbé egbòogi

Aláboyún méjì afurasí mìíràn rèé tí NDLEA mú láàrin ọsẹ tó kọjá ní Nàìjíríà

Igbiyanju ajọ to n gbe ogun ti lilo egboogi oloro tun ti ja si rere nipa bi ọwọ wọn se tẹ awọn aboyun meji kan ati awọn afurasi meji mii to fẹ gbe oogun oloro gba papakọ ofurufu ipinlẹ Eko lọ si oke okun.

Ni ọsẹ to kọja yi ni ọwọ palaba awọn taa n wi yi segi.

Alukoro ajọ naa Femi Babafemi lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.

Kini ajọ NDLEA sọ?

Babafemi ni ọkan ninu awọn afurasi to dari lati orileede Brazil,Nworie Philip Chikwendu,ni ọwọ awọn kọkọ tẹ lọjọ Kẹta, osu Karun.

O ni awọn ri i mu nigba to n gbiyanju lati gbe egboogi oloro wọ Naijiria lati Brazil.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Asiri tu nigba ti wọn tu ẹru rẹ ti wọn si ba egboogi oloro cocaine to ko pamọ sinu bata to ko pamọ sinu baagi agbepọnyin rẹ.

Wọn tẹsiwaju lati tu bata to wọ sẹsẹ ti wọn si tun ri pe o gbe cocaine meji pamọ sibẹ ti apapọ cocaine ti wọn ka mọ lọwọ si jẹ 800grams.

Nigba ti wọn bẹrẹ si ni fọrọ wa lẹnu wo, Nworie to si gẹri gẹri loun n se ni Brazil sọ pe oun wa si Naijiria pada lati wa sinku baba oun.

O jẹwọ pe ọrẹ rẹ kan to wa ni Sao Paulo lo fi isẹ oogun oloro tita lọ to si ni o fun oun ni miliọnu meji Naira toun ba gbe egboogi oloro wa si Naijiria.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Lọjọ Keji ọjọ yi laarin ọsẹ taa n sọ nipa rẹ,ajọ NDLEA da awọn paali ọti kan ti wọn fura si pe egboogi oloro wa ninu wọn.

Kia ni wọn ti mu arakunrin kan to n gbe ẹru wọle to si jẹ ẹni to gbe awọn ọti yi wọle lati Dubai,arakunrin Shola Ogunrinde.

Wọn lawọn tẹsiwaju iwadii awọn lẹyin ti wn mu Shola tan ti ọwọ si gba ibẹ tẹ obinrin alaboyun kan arabirin Seun Babatunde to ni ile ọti kan to wa ladugbo Iyana Ipaja.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Wọn si paali yi nisoju arakunrin Shola ati arabirin alaboyun yi ti wọn si ba aimọye igbo ati egboogi kan torukọ rẹ n jẹ ecstacy(MDAM) ninu agolo ọti yi.

Nigba ti arabirin Babatunde jẹwọ fun awọn ọlọpaa, o ni ọkọ oun to wa ni Dubau lo gbe awọn egboogi oloro yi ransẹ soun.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Alaboyun keji taa n wi ni arabinrin Gloria Asibor.

Lọjọ Karun un, osu karun un tii se Ọjọbọ ni panpẹ ofin mu nigba to fẹ wọ baalu kan lọ si Bolonia ni Spain gba Turkey.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Wọn tu ẹru to gbe lọwọ ti wọn si ri ounjẹ to gbe sinu rẹ.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Ninu ounjẹ yi ni wọn ti ba egboogi oloro tabilẹẹti Tramadol ti o ko si inu ede.