2022 Electoral act: Ilé aṣòfin àpapọ̀ yí òfin ìdìbò padà, wọ́n ní ààrẹ, gominà, àwọn aṣòfin àtàwọn míràn láǹfàní láti dìbò lásìkò ìbò abẹ́nú lẹ́gbẹ́ òṣèlú wọn

ileegbimọ aṣofin apapọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, other

Bi a ba ni eegun baba ẹni yoo jo, ti a tun fo fẹrẹ yi ohun pada pe ko ni jo mo mọ, alaagba kan kii mu ni sii.

Eyi gan an lo difa fun ileegbimọ aṣofin agba Naijiria to fọwọ si atunṣe tuntun si ofin eto idibo Naijiria tọdun 2022.

Wọn ṣe eyi lati lee fi aye gba awọn akanṣe aṣojudibo lẹgbẹ oṣelu kọọkan lati kopa tabi dibo lasiko ibo tabi ipade ati yan awọn oludije lẹgbẹ oṣelu koowa wọn.Wo àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú máa fi ń jẹ àwọn ènìyàn bí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́lé

Eyi waye lẹyin ti awọn aṣofin agba Naijiria naagbe igbesẹ pa-pa-pa lori abadofin atunṣe ofin naa.

Lara awọn ti aba naa ba wi gẹgẹbii akanṣe aṣojudibo lẹgbẹ oṣelu ni aarẹ, igbakeji aarẹ, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin, gomina atawọn igbakeji wọn, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ, awọn alaga kansu, kansilọ atawọn ọmọ igbimọamuṣẹya ẹgbẹ oṣelu gbogbo.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Nigba to n gbe aba naa kalẹ, igbakeji aarẹ ileegbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ, Ovie Omo-Agege toṣe agbatẹru abadofin lori atunṣe abala kẹrinlelọgọrin ofin eto idibo Naijiria naa ṣalaye pe abala naa ko fi aye silẹ fun ikopa awọn eeyan ti a pe ni akanṣe aṣojudibo naa ninu awọn ipade idibo ẹgbẹ oṣelu gbogbo.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

O ni awọn aṣojudibo ti wọn dibo yan sipo nikan lo faaye gba, to si ni 'aṣiṣe aimọọmọ da leyi, ti wọn si lee wa ojuutu si nipasẹ aba to wa niwaju ile aṣofin apapọ lọwọ yii."

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

O fi kun un pe bi ẹka ile aṣofin mejeeji ba lee tete ṣiṣẹ lori aba naa ki aarẹ lee buwọluu ko dofin lẹyẹ o ṣọka lati fun wọn lanfani kikopa lawọn ipade ẹgbẹ oṣelu kọọkan lati yan awọn oludije fun gbogbo ipo to wa fun didu lasiko eto idibo apapọ ọdun 2023 ti yoo bẹrẹ lọjọ kejidinlogun oṣu karun un, ọdun 2022 ati lẹyin rẹ.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá