Education: Ìjọba Oyo dá ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ìtàn "History" padà sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ijọba ipinlẹ Oyo ti pa laṣẹ fun awọn ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ni ipinlẹ naa lati bẹrẹ kikọ awọn akẹkọọ ni imọ nipa itan 'History' lati ibẹrẹ saa eto ẹkọ kẹta ti ọdun 2021/2022.
Alaga ajọ eto ẹkọ kari aye, SUBEB ipinlẹ Oyo, Dr Nureni Adeniran lo sọ eyi nigba to sẹ abẹwọ si awọn ile ẹkọ alakọọbẹrẹ kan ni ilu Ibadan.
Adeniran dupẹ lọwọ awọn alakoso ajọ SUBEB fun bi wọn ṣe pin iwe itan bi 4950 si gbogbo ileẹkọọ alakọbẹrẹ ni ipinle Oyo.
- Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Uche Igwe di èrò iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pínpín fídíò ìbálòpọ̀ ọmọdé
- Human Rights Watch fẹ̀sùn àìbìkítà kan ìjọba Naijiria lẹ́yìn ikú awọn olùwọ́de lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Báwo ni ọ̀rọ̀ ilé ṣe fa Gbas-gbos láàrín Mercy Aigbe, ìyáále rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀?
- Èmi ò gbé'ṣẹ́ rán ẹnikẹ́ni láti ra fọ́ọ̀mù ìdíje ààrẹ fún mi o, ẹ máà kóbá mi -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Jonathan fún Miyetti Allah lésì
- Kọ́ńdọ̀ọ̀mù méjìlá lá rí ní iyàrá ilé ìtura tí wọ́n ti fípa bá arábìnrin Ulochi lòpọ̀- Olọ́pàá
- Wo àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú máa fi ń jẹ àwọn ènìyàn bí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́lé
- Ìpapòda Aláàfin kò ní dá ètò ìfinijoyè Gbajabiamila dúró- Ọyọmesi
O ni awọn iwe itan naa yoo fun awọn akẹkọọ ni anfaani lati mọ nipa iṣẹlẹ to ti kọja ki wọn le loo fun idagbasoke agbegbe wọn ati orilẹ ede Naijiria lapapọ.
Alaga SUBEB Oyo tun fi kun pe dida ikẹkọọ nipa imọ itan pada si yara awọn akẹkọọ kii ṣe wi pe yoo wulo fun awọn akẹkọọ nikan, awọn ọlukọ ile ẹkọ alakọọbẹrẹ naa yoo jẹ anfaani rẹ gẹgẹ bi o sẹ wulọ fun awọn aṣiwaju.
- Ó pé ọdún 35 tí Obafemi Awolowo kú, wo àwọn nkan mánigbàgbé tí o kò gbọ́ rí nípa rẹ̀
- Adelabu kéde èròńgbà rẹ̀ láti jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo
- Ọwọ́ pálábá NDLEA tẹ aláboyún méjì, 'barber' kan àti àwọn afurasí mí tó gbé egbòogi
- INEC lẹ́tọ̀ọ́ láti bẹ́gi dínà èróngbà Emefiele láti díje du ipò Ààrẹ- Ilé ẹjọ́
- Irọ́ ni, irọ́ kọ́ Toyin Adegbola àti àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa fídíò Biola àti Olùdarí ere tí wọ́n jọ ní gbólóhùn asọ̀
- Mọ̀lẹ́bí ṣàlàyé kíkún nípa bí agbébọn ṣe ṣekúpa Gloria Mathew àti àfẹ́sọ́nà rẹ̀ nínú igbó ní ìpínlẹ̀ Imo













