South Africa KwaZulu-Natal Floods: Wọ́n ti sin òkú èèyàn bí 200 nínú 435 tí omiyalé pa

Ẹbí kan pàdánù ọmọ mẹsan-án nínú èèyàn 435 tí omiyalé pa
Inu ibanujẹ ati ìpayínkeke si ni awọn olugbe agbegbe KwaZulu-Natal, ni orile-ede South Africa wa, lẹyin iṣẹlẹ omiyale to pa eeyan 435 ni oṣù to kọja.
Iṣẹlẹ omiyale naa ni eyi to tíì buru ju ni orile-ede naa lati ọgọta ọdun.
Lọwọlọwọ, isinku apapọ ti n waye, bo tilẹ jẹ pe ọpọ idile ni ko ti le sin oku eeyan wọn, nitori pe àgbàrá gbe wọn lọ.
- Ẹkún tún sọ ní Zamfara, àwọn agbébọn pa èèyàn 48
- Èsì ìdánwò UTME abala àkọ́kọ́ yóò jáde lọ́sẹ̀ yìí- Àjọ JAMB
- Bí Jibrin ṣe kúrò ní ẹgbẹ̀ òṣèlú APC kò níi ṣe pẹ̀lú Bola Tinubu- Agbẹnusọ ìpolongo
- Kí nìdí táwọn iléeṣẹ́ bàlúù ní Nàìjíríà ṣe fẹ́ wọ́gilé ìrìnnà òfúrufú ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé?
- 'Mo bá ajá ní ìbálòpọ̀ nítorí ₦1.4m', ka ǹkan tí òfin Nàìjíríà ṣọ nípa ìwà yìí
- Wo ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní "ọ̀nà ikú" tí àwọn ènìyàn ṣì ń ṣe ìrìnàjò lórí rẹ̀ síbẹ̀
- Mo dúpẹ́ ó! Mo bẹ́ orí fún gbogbo àgbẹ̀ àti olùfọkànsìn tó ń dáwó fọ́ọ̀mù Ààrẹ fún mi àmọ́ ẹ jẹ́ n lo óògùn ara mi - Emefiele
- Ikú d'óró! Wole Adetiran tó kọ orin àdákọ àgùnbánirọ̀ Naijiria 'NYSC Anthem' ti jáde láyé
Kini oju akoroyin BBC to wa nibẹ ri?
Akọroyin BBC to lọ si agbegbe naa, sọ pe idile kan wa to padanu ọmọ mẹsan-an, ati iya kan.
Oju orun ni omiyale naa ba Arabinrin Slindile Mdalose, ẹni ọdun mẹtalelogojj, ati ọmọ mẹsan-an, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdún meji si mẹwaa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Niṣe ni omi àgbàrá ya wọ inu ile wọn, to si wó lulẹ.
Wọn ti sin oku obinrin naa, ati awọn ọmọ rẹ marun-un.
Wọn ko tii ri oku awọn ọmọ mẹrin to kù, to jẹ ibatan obinrin ọhun.
Bo ṣe ri ninu ẹbi Mdalose, naa ni ibanujẹ kun ile awọn ẹbi eeyan yooku lara awọn 435.
Ogunlọgọ ni wọn ko tii ri oku wọn.
Wọn ti sin awọn to din ni igba, oku eeyan mọkandinlọgọta si wa ni mọṣuari.

Oju wo ni Aare South Africa di wo iṣẹlẹ yii?
Aarẹ Cyril Ramaphosa sapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi òfò nla ni fun orile-ede naa.
O ni awọn si nilo owo si ju miliọnu mejidinlaadọrin Dọla, ti ìjọba ti ya sọtọ lati fi mu agbegbe KwaZulu-Natal pada sipo.
Ijọba si ti n wa ilẹ ti yoo fi kọ ibugbe fun ẹgbẹẹgbẹrun eeyan to di alainilelori jakejado agbegbe naa.
- Bíbéli mi ló sọ pé kí n fẹ́ ìyàwó omidan mẹ́rin, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀- Pásítọ̀
- A kọ̀ láti yí ọkàn wà padà lórí ìpinnu Yorùbá Nation- Ilana Omo Oodua
- Afurasí Oníṣòwò ǹkan ìjà olóró méje kó sí pańpẹ́ Ọlọ́pàá ní Jos àti Taraba
- Mi o rí òṣèrékùnrin tí kìí yan àlè lẹ́yìn ìyàwó wọn- Iyabo Ojo
- Wòlíì Olubọla ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jí ọkọ̀ ọmọ ijọ̀ lọ ní Abeokuta
- Mo bẹ̀rẹ̀ sí ń wọ ìjáàbù nítorí àwọn okùnrin máa ń wo bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí mi tí mo bá ń wàásù - Sister Kate
- Wo ohun mánigbàgbé mẹ́fà nípa Gbenga Adeboye lẹ́yìn ọdún 19 tó kú













