Godwin Emefiele: Mo bẹ́ orí fún gbogbo àgbẹ̀ àti olùfọkànsìn tó ń dáwó fọ́ọ̀mù Ààrẹ fún mi àmọ́ ẹ jẹ́ n lo óògùn ara mi

Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gomina banki àpapọ̀ orílẹ̀èdè Naijiria, Godwin Emefiele tí fi ọrọ idupẹ ránṣẹ́ sì awọn kan to ni wọn kórajọ lati ra fọ́ọ̀mù oludije ipo Ààrẹ fun un.

Emefiele fi sita loju opo Twitter rẹ pe irẹlẹ wọ oun lẹwu gidi pẹlu iru ifẹ ti awọn to n pe oun lati wa dije du ipo Ààrẹ lọdun 2023 ni si oun.

Bo tilẹ̀ jẹ pe o ni oun ko tii de bi ìpinnu yii, o ni oun mọ riri ifarajin "awọn àgbẹ̀ àtàwọn olùfọkànsìn ọmọ Nàìjíríà to n ṣe akitiyan de bi pe wọn n da owo lapo ara wọn ti wọn si n náwó fọ́ọ̀mù lati du ipo Ààrẹ si mi.

Mo dupẹ lọwọ wọn pupọ ".

Ẹwẹ, Emefiele ni bi oun yoo ba tiẹ̀ wa gbọ́ si wọn lẹ́nu lati dije du ipo Ààrẹ, owo ara oun ti oun laagun ko jọ ni ọdun marunlelọgbọn lẹ́nu isẹ banki gẹgẹ bi ọga agba ni oun yoo fọ́ọ̀mù oun "lai ran ẹnikẹ́ni, ni gbangba àti pẹlu ọwọ mimọ àti ni ibamu pẹlu alakalẹ ìwé ofin Naijiria".

Bo ba tun wa ri bẹẹ, Emefiele ni oun yoo tesiwaju lati maa sin àti farajin fawọn ọmọ orílẹ̀èdè Naijiria lábẹ́ akoso Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Gomina ilé ifowopamọ Naijiria sọ pé: "Ipinu to ṣe pataki ni eleyi to si nilo ìlọ́wọ́ sí Ọlọ́run ; ni ọjọ díẹ̀ to ku, Ọlọ́run alagbara yoo dárí".

Ṣe gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà lè díje dupò Ààrẹ? Àlàyé rèé

EMEFIELE

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA

Láti ìgbà tí àwọn kan ti ra fọ́ọ̀mù ìdíje dupò Ààrẹ fún gómìnà ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, Godwin Emefiele ni awuyewuye ti ń wáyé wí pé ǹjẹ́ ó lẹ́tọ̀ọ́ láti dupò Ààrẹ.

Àgbà onímọ̀ ìṣirò owó kan tó tún jẹ́ olóṣèlú, Hussein Olanrewaju Mustapha nígbà sọ fún BBC News Yorùbá wí pé kò sí òfin kankan lábẹ́ òfin tó dé ìlòdì sí àwọn òṣìṣẹ́ báńkì Nàìjíríà yálà aládani tàbí ti ìjọba láti dupò òṣèlú.

Mustapha ní kò sí ohun tó burú tí gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà bá gbégbá láti di Ààrẹ Nàìjíríà níwọ̀n ìgbà tó bá ti tẹ̀lé àlàkalẹ̀ ìwé òfin Nàìjíríà.

Ó fi kún un pé lóòótọ́ ni òfin ìlànà ètò ìdìbò tuntun tí Ààrẹ Muhammadu Buhari buwọ́lù láìpẹ́ yìí làá kalẹ̀ wí pé ẹnikẹ́ni tó bá dipò òṣèlú mú gbọ́dọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀ fún iye ìgbà kan kó tó gbégbá ìbò.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀gá ni ooru Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ orílẹ̀èdè ti mo ti wálé; Bí mo ṣe parí iṣẹ́ 'AC' tó ń ló iná òòrùn rèé'

Ó ní èyí tako ìwé òfin Nàìjíríà tó fi àyè gba gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti dìbò tàbí du ipò tó bá wù ú lábẹ́ òfin.

Ó wòye wí pé èyí ló fà á tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Mínísítà tó ti kéde èròńgbà wọn láti díje dupò òṣèlú kan tàbí òmíràn fi kọ̀ láti kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀.

Bákan náà ló tẹ̀síwájú wí pé òfin fi àyè gba Emefiele láti dú ipò tó bá wù ú tàbí ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá wù ú láì tàpá sófin.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Gomina Banki apapọ Naijiria Godwin Emefiele naa ti ṣetan lati darapọ mọ awọn to n gbero lati du ipo aarẹ Naijiria ni kete ti saa aarẹ Buhari ba de opin.

Lọjọ Ẹti yi ni awọn ololufẹ rẹ kan lọ ba gba fọọmu iferongba silẹ lati du ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ APC ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa lAbuja.

Ẹni ọgọta ọdun yi ni Gomina Banki apapọ akọkọ ninu itan Naijiria ti yoo ṣe iru nkan bayi.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'

Eleyi si ti mu kawọn eeyan maa beere pe ṣe o lẹtọ labẹ ofin Naijria lati dije du ipo aarẹ.

Bi Emefiele ba tẹsiwaju pẹlu erongba rẹ yi, oun ati awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC bi igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ati awọn Gomina tẹlẹ ri mi ati awọn mii to wa lori ipo ni yoo jijọ maa figa gbaga nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Bákan náà ni yóò máa wako pẹ̀lú àwọn èèkàn bíi Atiku Abubakar, Bukola Saraki àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà, ọdún 2022 ni àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú di tí wọ́n yóò fi fi orúkọ àwọn olùdíje kalẹ̀.