2023 Presidency: Èsì Ààrẹ Buhari lórí ẹni tó jẹ́ ààyò rẹ̀ tí aráàlú ń bèrè nìyí

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ to wípé ó ní ààyò nínú gbogbo àwọn olóṣèlú tí wọ́n ti fi èròńgbà wọn léde láti di Ààrẹ Nàìjíríà ní kété tí òun bá fi àpèrè náà sílẹ̀ lọ́dún tó ń bọ̀.
Buhari ní òun kò ní ẹnìkan lọ́kàn tí òun fẹ́ kó di Ààrẹ lẹ́yìn òun àyàfi ẹni tí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá dìbò fún.
Ó ní ẹni tí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá ti yàn níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò darí wọn fún ọdún mẹ́rin ni òun yóò fa ìṣàkóso orílẹ̀èdè yìí lé lọ́wọ́.
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn tó kírun yídì tán.
Ní Bárékè Mambilla tó wà ní ìlú Abuja ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kírun yídì ọdún ìtúnu àwẹ̀.
Ààrẹ Buhari rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti jí gìrì sí iṣẹ́ wọn.
Bákan náà ni Ààrẹ Muhammadu Buhari tún rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò orílẹ̀ èdè yìí láti túnbọ̀ jí gìrì sí ojúṣe wọn, kí wọ́n ri dájú pé ààbò tó péye wà fún tolórí tẹlẹ́mù Nàìjíríà.
Ó rọ̀ wọ́n láti sa gbogbo ipá wọ́n láti ri pé wọ́n gbógunti ìpèníjà ètò ààbò tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́.
Ó fi kun pé ó pọn dandan kí àyíká wà nínú ààbò tó péye pàápàá lásìkò òjò yìí kì àwọn àgbẹ̀ le padà sóko kí oúnjẹ le pọ̀ yanturu ní Nàìjíríà.
Ààrẹ Buhari sọ síwájú pé gbogbo àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ ti orí ilẹ̀, ojú omi àti ti òfurufú ló mọ ìpèníjà tí Nàìjíríà ń dojú kọ, tó sì ní iṣẹ́ wọn ni láti wá àwọn agbéṣùmọ̀mí náà rí, kí wọ́n sì pá wọ́n tán.
Ṣaájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọdún tí Ààrẹ Buhari fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kìíní, oṣù karùn-ún ni ó ti tẹmpẹlẹmọ wí pé ìṣèjọba òun ní ìfarajìn sí fífi òpin sí àìsí ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjà náà lè díẹ̀, tó sì ti ń lọ fún ọjọ́ pípẹ́, òun ní ìgbàgbọ́ wí pé dídùn ni ọsàn yóò so nígbẹ̀yìn.


















