2023 Elections: Àjọ INEC sọ ìdí tí káàdì olùdìbò lè fi kọṣẹ́

Kaadi idibo lori tabili

Oríṣun àwòrán, INEC Nigeria/Facebook

Ni ọjọru ni alaga apapọ ajọ INEC lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu kede pe miliọnu kan o le ẹgbẹrun mẹrindinlaadoje kaadi idibo tawọn eeyan ṣẹṣẹ gba ni ko ni ṣiṣẹ.

Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ, Ọjọgbọn Yakubu ni ko din lẹgbẹrun mẹtadinlogun kaadi idibo tawọn oludibo nipinlẹ Ekiti n gbe kiri ti ko lee ṣiṣẹ.

Bakan naa lo ni kaadi idibo mejidinlaadọrun lo wa lọwọ awọn oludibo nipinlẹ Ọṣun ti ko ṣiṣẹ pẹlu

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbogbo eyi n waye pẹlu bo ṣe jẹ pe eto idibo gomina l'Ekiti ati Ọṣun yoo waye loṣu kẹfa ati ikeje ọdun 2022.

Ìdí mẹ́ta tí káàdì ìdìbò rẹ̀ kò fi ní wúlò mọ́:

Eyi ni awọn ohun meje ti ajọ INEC yan ninu atẹjade naa pe o ṣeeṣe ko mu ki kaadi idibo o maa ṣiṣẹ.

  • Bi o ba forukọ silẹ lati gba kaadi idibo ju igba kan ṣoṣo lọ.
  • Bi oludibo ko ba fi gbogbo iroyin to yẹ silẹ lasiko ti wọn ba n ṣe iforukọsilẹ rẹ.
  • Aini imọ to kun to nipa igbesẹ iforukọsilẹ. Ajọ INEC si ṣalaye pe oun yoo gbe igbesẹ lati ṣe agbekalẹ ẹka ti yoo wa fun ilanilọyẹ fawọn to ba fẹ forukọ silẹ lati gba kaadi idibo.

Gẹgẹbi ohun to sọ, Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood ni ida marundinlaadọta awọn kaadi idibo awọn ti wọn ṣẹṣẹ forukọsilẹ fun kaadi idibo naa ni ko ni ṣiṣẹ nitori awọn idi to wa loke yii.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

O fi kun pe awọn tun kẹẹfin pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan n lẹdi apopọ pẹlawọn eeyan kan lati tapa si ofin idibo Naijiria to de eto iforukọsilẹ.

O ni gbogbo awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti aje iṣẹlẹ naa ba ṣi mọ lori ni yoo foju wina ofin ni ibamu pẹlu awọn abala to yẹ labẹ ofin idibo ni Naijiria.

O ni gbogbo awọn ti kaadi idibo ti ko dara wọnyii ni wọn yoo yọ danu kuro ninu iwe orukọ awọn oludibo.

O tun ṣalaye pe ko si ipinlẹ ti aṣemaṣe yii ko ti waye lorilẹede Naijiria debi pe awọn ipinlẹ mii wa to jẹ pe ida ọgọta lawọn kaadi ti ko ni ṣiṣẹ naa.

Amin iyasọtọ kan

Àjọ INEC ní àwọn káàdì ìdìbò kan kò wúlò mọ́ láti fi dìbò lọ́dún 2023

Àwọn olùdìbò

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Àwọn olùdìbò

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC ti ní ìdá mẹ́rìnlélógójì àwọn káàdì ìdìbò tí wọ́n fi léde láti ọdún tó kọjá títí di àsìkò yìí ni kò ní wúlò láti fi dìbò.

Alága àjọ INEC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakub ní 1,390,519 ènìyàn péré ló fi orúkọ sílẹ̀ fún káàdì ìdìbò láti ìgbà tí àjọ náà ti bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ fún káàdì ìdìbò mìíràn ní ọdún 2021.

Ní ibi àpérò tí Yakubu ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Abuja lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kẹrin, ọdún ló ti fi ọ̀rọ̀ náà léde.

Ó ní ìpèníjà ńlá ni èyí jẹ́ nítorí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn gbọ́dọ̀ tún lọ fi orúkọ sílẹ̀ kí wọ́n tó le kópa nábi ètì ìdìbò.

Bákan náà ló tún fi kun un wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́wàá nínú àwọn méjìdínlógún ni won ti i ri.

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Kini Alaga INEC tun salaye?

O ni eyi je ninu awon tó jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó jẹ́ ojúlówó ní Nàìjíríà ló fi ìgbà tí wọ́n yóò ṣe ètò ìdìbò abẹ́nú wọ́n ṣọwọ́ sí àjọ náà.

Yakubu wá rọ àwọn ẹgbẹ́ yòókù náà láti tété fi ìgbà tí wọ́n yóò ṣe ètò ìdìbò náà tó wọn létí kí ọjọ́ tó lọ lórí rẹ̀.