Fake Army: Iléeṣẹ́ ológun ní àádọ́jọ́ ayédèrú ológun ní ọwọ́ òun ti tẹ̀ láti oṣù kínní 2022

Awọn ayederu ologun mejila

Oríṣun àwòrán, 81 Division Army

Kò dín ní afurasí méjìlá tí wọ́n ń pera wọn ní òṣìṣẹ́ àjọ ọmọ ogun ilẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko àti Ogun ni ẹ̀ka 81 àwọn ọmọ ogún ti nawọ́ gán.

Àwọn afurasi náà ló wọ aṣọ ọmọ ogun láti máa fi ṣe iṣẹ́ àìtọ́ láàárín ìpínlẹ̀ Eko àti Ogun.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun ẹ̀ka 81, Umar Thama Musa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbogbo àwọn ìwà ibi tí àwọn tó bá wọ aṣọ ológun bá wọ̀ kò túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ ogun ló wu ìwà bẹ́ẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Musa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó máa ń fi bẹ́lìtì àti àwọn tíkẹ̀ẹ̀tì sára ọkọ̀ àti àwọn tó máa ń wọ aṣọ ológun kiri nínú ọkọ̀ èrò láti fi máa halẹ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ni kìí ṣe ológun tòótọ́.

Ó ní ètò "OPERATION CHECKMATE" tí àwọn gùnlé nígbà tí àwọn ti ń wòye wí pé irúfẹ́ àwọn ayédèrú ènìyàn tó ń pe ara wọn ní òṣìṣẹ́ ológun ló ń tú àṣírí àwọn oníṣẹ́ ibi náà.

Ó fi kun wí pé àádọ́jọ àwọn èké tó ń pe ara wọn ní òṣìṣẹ́ ológun ni àwọn ti nawọ́ gán láàárín oṣù kìíní ọdún yìí sí àsìkò yìí.

Awọn ayederu ologun mejila

Oríṣun àwòrán, 81 Division Army

Ọ̀pọ̀ wọn ló ń gbégi dínà gbowó lọ́wọ́ àwọn ènìyàn

Bákan náà ló sọ síwájú pe ìwádìí fi hàn wí pé àwọn tí wọ́n nawọ́ gán náà ló máa ń gbégi dínà ní àwọn òpópónà ní agbègbè Ajah, láti fi gba owó lọ́wọ́ àwọn ará ìlú.

Bẹ́ẹ̀ náà ló tún ní àwọn mú àwọn kan tí wọ́n wà ní ẹnu ibodè Ilaro tí wọ́n wọ aṣọ ológun láti máa fi kó àwọn ọjà tí ìjọba ti fòfin dè wọlé.

Ó ní àwọn yóò fa àwọn afurasí náà le àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ fún ìjìyà tó yẹ.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti yé wọ aṣọ ológun láti ràn wọ́n lọ́wọ́ lójúnà àti yọwọ́ àwọn oníṣẹ́ ibi kúrò láwon àwùjọ.