Uganda researcher killed: Ramirez Amaya Sebastian dèrò ọ̀run lẹ́yìn ti erin kan kọlùú ni agbègbè Kibale

Erin uganda

Oríṣun àwòrán, others

Erin kọlu Amaya Sebastian, àgbà ọ̀jẹ́ ọjọ́gbọ́n nínú isẹ́ ìwádìí kan, ikú ló padà já sí

Agba ọ̀jẹ̀ onimo sayensi Ramirez Amaya Sebastian dero ọ̀run ni Uganda.

Ramirez Amaya Sebastian ni awon alase to n mojuto igbo lorile ede Uganda fi ikede sita nipa re leyin to jade laye.

Bawo ni ọ̀rọ̀ se sele?

Uganda Wild life Authority, (UWA) fi atejade sita nipa oọ́gbon onise iwadii Ramirez Amaya Sebastian to wa lati Fasiti kan ni orile-ede America.

Won ni o ti n se ise iwadii naa lo lati igba die ni igbo oba kan ni agbegbe Kibale pelu oluranlọ́wọ́ rẹ̀.

UWA so pe laipe ni won salabapade erin kan to da duro ninu igbo Oba naa ni eyi to si kolu awon mejeeji.

Agbenuso UWA, Bashir Hangi salaye pw erin naa tele Sebastian to si tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ ni eyi to je ki ọjọ̀gbọ̀n naa di ero ọ̀run.

Awon alase Uganda ni pe ikolu erin si Sebastian yii ni Kibale ni igba akọ́kọ́ ti eyi yoo sele ni Igbo Oba naa laarin aadota odun seyin.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

Kini o ti sele seyin nipa iru isele bayii?

Ninu osu kinni odun yii ni arinrinajo kan lati orile-ede Saudi Arabia naa kagbako erin kan.

Agbegbe Murchison to je igbo Oba omiran ni oeilre ede Uganda ni eyi ti sele.

Leyin ti erin naa te arinrinajo Saudi yii mole tan ni oun naa dero ọ̀run.

O pade erin yii lasiko to fi awon akegbe rẹ̀ ti wan jọ́ n rinrinajo afẹ́ silẹ ninu ọkọ̀ ti gbogbo wọ́n jọ wa.