Tinubu-Osinbajo 2023 Ambition: Ìdí tí Tinubu fi ṣèpàdé pẹ̀láwọn gómìnà APC lẹ́yìn tí Osinbajo kéde lati díje fun ipo aarẹ̀ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, other
Igbaradi fun eto idibo apapọ 2023 lorilẹede Naijiria ti n ṣarajọ bayii, oniruuru awọn oludije lo si ti n ko ina mọ aaro erongba wọn.
Ni ọjọ Aje ni igbakeji aarẹ lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo fi erongba rẹ han lẹyin to ti kọkọ fi ọrọ to awọn gomina to wa labẹaṣia ẹgbẹ oṣelu APC leti lalẹ ọjọ Aiku.
Amọ nibayii, aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa, Ahmed Bọla Tinubu pẹlu ti ṣepade pẹlu awọn gomina lẹgbẹ oṣelu APC nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ tètè jápa tí ìgbéyàwó yín bá ti la ìgbájú-ìgbámú lọ - Olori Silekunola
- Ìdí tí Tinubu fi ṣèpàdé pẹ̀láwọn gómìnà APC lẹ́yìn tí Osinbajo kéde lati díje fun ipo aarẹ̀ ní Nàìjíríà
- Àwọn ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ òfin gbé ọkọ olórin ẹ̀mí “Ekwueme” fẹ́sùn lílu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú
- Àwọn agbébọn ṣekúpa alága APC ní ìpínlẹ̀ Osun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé Osinbajo dalẹ̀ Tinubu pẹ̀lú bó ṣe kéde láti du ipò ààrẹ?
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn agbébọn pa ènìyàn 135 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Àwọn ọmọ Palestine kọlu ìbòjì Josẹfu ọmọ Jakọbu, wọ́n dáná sun-ún
Ni alẹ ọjọ Aje ni iroyin ti kan pe ọrọ laarin Tinubu ati Oṣinbajo ti n gbona diẹdiẹ, ti o si mu ki agba oṣelu naa o ṣepade pẹlu awọn gomina lẹgbẹ oṣelu naa.
Amọṣa Bọla Tinubu ti kede faye gbọ pe ko si idi meji ti ipade oun atawọn gomina naa fi waye ju lati tun bu wọn gbọ nipa ilepa oun lati gba ipo aarẹ lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to ba parii saa iṣejọba rẹ.
Awọn gomina to wa nibi ipade naa ni Abubakar Bagudu (Kebbi), Nasir El-Rufai (Kaduna), Bababjide Sanwo-Olu (Eko), Abdullahi Ganduje (Kano), Gboyega Oyetola (Osun), Mai Mala Binu (Yobe), Simon Lalong (Plateau), Abubakar Badaru (Jigawa) atawọn miran.
Ko pe wakati mẹrinlelogun lẹyin ti igbakeji aarẹ Yẹmi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023, ti ipade naa waye.
Ki ni Tinubu sọ lẹyin ipade naa?

Oríṣun àwòrán, other
Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ṣalaye fun awọn akọroyin lẹyin ipade naa pe, ara ọna lati wa atilẹyin awọn gomina naa fun ilepa oun lati di aarẹ Naijiria lo fa ipade naa.
"Idi ti mo fi wa sibi ni lati beere fun atilẹyin, ajọṣepọ ati iwuri ẹgbẹ oṣelu mi, APC fun erongba mi lati di aarẹ orilẹede Naijiria nigba ti aarẹ Muhammadu Buhari ba pari saa rẹ lori oye."
Amọṣa nigba ti wọn bii nipa ohun to ri si ikede Osinbajo, ẹni ti ọpọ mọ gẹgẹ bii kan lara awọn ọmọ rẹ lagbo oṣelu, lati du ipo aarẹ ọdun 2023 pẹlu rẹ, Tinubu ṣalaye pe "oun ko tii bi ọmọ to dagba to lati lati ṣe irufẹ ikede bẹẹ."
O fi kun un pe bi ọpọ oludije ṣe n jade lati dije yii fihan pe ọja to ta lẹnuni ẹgbẹ oṣelu naa fun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria.
Idaniloju wo lawọn gomina naa fun Tinubu?
Gomina Bagudu tipinlẹ̀ Kebbi lo gbẹnu sọrọ fun awọn gomina to wa nibi ipade naa. O ni Tinubu ṣe ipade pẹlawọn gomina naa lati lee fi to wọn leti nipa ipinnu rẹ lati dije du ipom aarẹ lorilẹede Naijiria.
O nigbogbo awọn gomina naa lo tẹti bẹlẹjẹ gbọ ohun ti Tinubu sọ lori erongba rẹ, idi to fẹ fi dije ati ohun gan to ni lọkan bi o ba wọle
O ni oun ti fesi fun Tinubu pe awọn yoo lọ gbe e yẹwo lati jiroro lori abajade wọn nipa rẹ.

Oko kìí jẹ́ ti baba tọmọ kó mà ní ààlà; Mi ò ní ọmọ tó dàgbà tó le jáde láti dupò Ààrẹ- Tinubu

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ọrọ ti fẹ maa sebi a n ta oko ọrọ si ara ẹni laarin agbaọjẹ asiwaju ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC) nii Bola Tinubu ati igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinbajo.
Gbogbo rẹ ko si kọja pe igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo ati Bola Tinubu jijọ fẹ mu omi ninu koto kanna fun ipo aarẹ Naijiria.
Adarí àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ní òun kò ní ọmọ tó dàgbà tó le dìde láti gbégbá ìdìbò sípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí.
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé Osinbajo dalẹ̀ Tinubu pẹ̀lú bó ṣe kéde láti du ipò ààrẹ?
- Àwọn agbébọn ṣekúpa alága APC ní ìpínlẹ̀ Osun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn agbébọn pa ènìyàn 135 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ yín, ẹ má bú ọkọ mi mọ́ torí ìgbéyàwó wa tó túká - Yewande Adekoya
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Àwọn ọmọ Palestine kọlu ìbòjì Josẹfu ọmọ Jakọbu, wọ́n dáná sun-ún
- "Ẹ̀yin onítíátà, ẹ gbàdúrà fún Kemi Afolabi, Ọlọ́run nìkan ló mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò já sí"
- Oluwo ṣe àbẹ̀wò sí Aláàfin lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó gbé ìyàwó tuntun
- Àgùnbánirọ̀ ya fọ́tò Bàbá Onílù láti tà á, òjò owó rọ̀ fún bàbá
- Bí Sunday Igboho bá sọ èròǹgbà rẹ̀ nípa Yoruba Nation, inú gbogbo ọmọ Yorùbá yóò dùn - Banji Akintoye
- Tí mo bá di ààrẹ, ìwúrí ni màá jẹ́ fọ́mọ Nàíjíríà - Tunde Bakare
Ko pẹ pupọ si igba ti Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati du ipo aarẹ ti Bola Tinubu ti tako ọrọ akọkọ si Osinbajo.
Gomina ipinle Eko yii nigba kan ri ta ọrọ mọ Osinbajo lasọ nigba to n se ipade pẹlu awọn Gomina ẹgbẹ APC.
Lasiko ipade yi,Tinubu sọ fawọn Gomina naa nipa erongba rẹ lati du ipo aarẹ lọdun 2023.
O sọ fun wọn pe "erongba mi ni lati wa ajọsepọ yin ati atilẹyin ẹgbẹ mi, ẹgbẹ APC fun ero mi lati jẹ aarẹ orileede Naijiria''
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ pe ko fesi si iroyin pe ọmọ rẹ, iyẹn Osinbajo ti kede erongba rẹ lati dupo aarẹ,Tinubu sọ pe ''Mi o ni ọmọ kankan to dagba debi pe yoo kede erongba lati du ipo aarẹ''
Ọrọ yi ni igba akọkọ ti Tinubu yoo sọrọ nipa erongba Osinbajo lati du ipo aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Tinubu ati Osinbajo-Baba ati ọmọ to fẹ mu omi ni koto kan
Ni ọdun 2015 ni Tinubu gbero lati du ipo gẹ́gẹ bi igbakeji aarẹ Buhari.
Ohun to yẹ erongba yi nigba naa ni pe wọn ni ko ni rọrun lati dije labẹ tikẹẹti musulumi meji nitori musulumi ni Tinubu ati Buhari.
Agbaọjẹ ẹgbẹ APC yii wa fa Yemi Osinbajo kalẹ lati ba Buhari dije gẹgẹ bi igbakeji rẹ.
Iru adehun to wa laarin awọn mejeeji ko han si wa sugbọn Osinbajo ti sisẹ labẹ ijọba Tinubu nigba to jẹ Gomina gẹgẹ bi kọmiṣọna feto idajọ.
Lọpọ igba ni Osinbajo ti maa n sọ nita gbangba pe oloore oun ni Tinubu lagbo oselu Naijiria ti ko si ko iyan Tinubu kere rara.
Amọ bayii ti Osinbajo ti wa kede pe oun naa fẹ jẹ ninu nnkan ti Tinubu ti n gbẹ oungbẹ rẹ lọjọ pipẹ, a ko mọ bi awọn mejeeji yoo se ba ara wọn se.
Tani Aarẹ Buhari yoo ṣe atilẹyin fun laaarin Tinubu ati Osinbajo?
Ibeere yi ni ọpọ onwoye Naijiria n wa idahun si lati igba to ti jọ pe Osinbajo ati Tinubu yoo jijọ gbe apoti ibo aarẹ Naijiria.
O si jẹ ibeere pataki nitori awọn mejeeji sunmọ Aarẹ́ Muhammadu Buhari.
Ni igun kan, Tinubu lo da bi alatilẹyin to sokunfa bi Muhammadu Buhari ti se de ipo aarẹ lẹyin igba mẹta to gbiyanju lati jẹ aarẹ.
Lapa keji, Osinbajo ati Buhari jijọ ni ajọsepọ to munadoko gẹgẹ bi aarẹ ati igbakeji.
O sọwọn lagbo oselu Naijiria lati ri iru ajọsepọ bayiI ti ọpọ si ri Osinbajo gẹgẹ bi ẹni ti Buhari fi ọkan tan lati tẹsiwaju gbogbo adawọle ijọ́ba rẹ.
Titi di ba se n sọrọ yi aarẹ Buhari ko sọ ẹni ti oun yoo se atilẹyin fun ninu idibo gẹgẹ bi aarẹ.
Ohun ti aarẹ Buhari sọ ni pe'' ti mo ba darukọ ẹni ti mo nifẹ si ko jẹ aarẹ, ko dami loju pe wọn ko ni seku pa''
Aarẹ ko darukọ ẹni ti yoo pa onitọun tabi ẹni to fẹ se atilẹyin fun yii.



















