Osun Killings: Àwọn agbébọn ṣekúpa alága APC ní ìpínlẹ̀ Osun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Gbenga Ogbara

Oríṣun àwòrán, Leadership

Àkọlé àwòrán, Gbenga Ogbara

Inu ibanujẹ ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC wa ni ipinlẹ Ọsun lẹ́yìn ti iroyin iṣekupa eekan ẹgbẹ naa kan lati ọwọ awọn agbébọn gbode.

Eni táa n wí yí gẹgẹ bí iroyin to tẹ wa lọwọ ni alaga ẹgbẹ ni ijọba ibilẹ ìlà oòrùn Atakumosa, Gbenga Ogbara.

Iroyin sọ pé l'owurọ kutu ọjọ Aje yii ni awọn agbébọn lọ ka mọlé rẹ ni Igangan ti wọn sì d'ẹmi rẹ legbodo.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa n'ipinlẹ Osun Yemisi Opalola fidi iṣẹlẹ yi múlẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wí, o ni ileeṣẹ ọlọpaa n tẹsiwaju pẹlu iwadii ati pe ko ni pẹ tàwọn yoo fi mu awọn to wa nidi iṣẹlẹ aburu yi.

Opalola ni: "Nnkan bi ago mejila oru ni awọn agbébọn ṣekupa alága APC. Ileese ọlọpaa sí ti fi awọn agbofinro ranṣẹ sí agbegbe naa.

"Iwadii ti bẹrẹ, kò sí ní pẹ tí ọwọ yóò fi tẹ awọn to wa nidi iwa aburu yi. Wọn kò ní lọ laijiya"

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀