Man Fights Lion in Ugandan: Àwọn ara abúlé yarí láti sun kìnìún tó kọlù wọn jẹ

Ọkunrin to ba kiniun ja ati oku kiniun

Oríṣun àwòrán, @isaacjabaniF

Iroyin nla ti gba ori ayelujara kan nipa ọkunrin kan to ba kiniun ja, to si wa ni aaye.

Isẹlẹ naa lo waye ni abule meji ọtọọtọ ni ẹkun Kagadi lorilẹede Uganda ni ọjọ Satide, ọjọ Kẹsan osu Kẹta ọdun 2022.

Aayan ọkunrin naa lati koju aaye kiniun yii lo n se ọpọ eeyan ni haa hii, ti wọn si ri ọkunrin naa bii ẹni ti Ọlọrun da, ti ko se fi ara we.

Gbogbo eeyan lo si n ki ku oriire pe ko ba isẹlẹ naa lọ nitori aja to lọ sile ẹkun, to bọ layọ ni ọrọ rẹ, o yẹ ka ki ku ewu.

Bawo ni isẹlẹ naa se waye?

Ninu iroyin kan ti ileesẹ to wa fun amojuto awọn ẹranko igbẹ lorilẹede Uganda, eyiun Uganda Wildlife Authority (UWA) fisita, wọn ni awọn ko mọ orisun ibi ti kiniun naa ti wa.

Wọn ni bi kiniun naa si se rin lọ kọlu awọn ara abule mejeeji ni ko ye awọn.

Awọn abule naa ni abule Kobushera ati Rwabaragi ti wọn wa ni agbegbe igberiko Mpeefu ni ẹkun Kagadi.

Kiniun naa, to ya wọ awọn abule yii lọjọ Ẹti, lo pa ọpọlọpọ ẹran ile bii ewurẹ, aja, aguntan, ologbo ati bẹẹ bẹẹ lọ da silẹ bẹẹrẹ b.

Bakan naa ni kiniun ọhun ko tun yọ awọn ara abule naa silẹ nitori se lo kọlu ọpọ wn, to si se wọn lese lọ jantirẹrẹ.

Ọna lati gbẹsan lara kiniun apanijaye naa lo mu kawọn ara abule naa ko ara wọn jọ, ti wọn si doju ija kọ kiniun naa.

Ta ni ọkunrin to fi ara gbọgbẹ lọwọ kiniun, ti aworan rẹ wa lori ayelujara?

Ọkunrin to ba kiniun ja

Oríṣun àwòrán, @isaacjabaniF

Iroyin kan ti Isaac Jabani gbe soju opo Twitter rẹ ni ọkan lara awọn ara abule naa ti wọn ko darukọ rẹ, gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, lo se aya gbaagbaa lati doju ija kọ kiniun naa.

Ọkunrin naa ni ko mu ohun ija lọwọ, to si fi ọwọ rẹ lasan ba kiniun ja.

Bi o tilẹ jẹ pe iroyin to n lọ lori ayelujara ni pe ọkunrin naa lo fi ọwọ rẹ lasan pa kiniun ọhun amọ awn alasẹ to wa fun akoso ẹranko igbẹ naa ti tako iroyin ọhun.

Ọkunrin to ba kiniun ja naa si ni aworan rẹ ti gba ori ayelujara kan, ti ko wọ asọ kankan sọrun ayafi sokoto to wa nidi rẹ nikan.

Sokoto naa si lo ti kun fun ẹjẹ balabala, ti ọpọ ọgbẹ si wa yika ara rẹ, eyi ti wọn ni kiniun ọhun lo fi awọn egbo naa sibẹ.

Awọn oju ọgbẹ kiti kiti to wa lara ọkunrin yii si ni wọn ti fi pilasita si eyi to fihan pe o ti lọ sile iwosan lati gba itọju.

Oku Kiniun

Oríṣun àwòrán, UWA

Ta lo pa kiniun, se ọkunrin yii ni abi awọn alasẹ ọgba ẹranko?

Ninu iroyin ti ileesẹ UWA fisita lẹyin isẹlẹ naa, wọn ni lootọ ni awọn ara abule naa ti doju ija kọ kiniun ọhun ki awọn to de sibẹ.

Amọ wọn ni kii se ọkunrin to siwaju awọn eeyan to kọlu kiniun naa lo pa.

UWA ni ifọwọsowọpọ awọn osisẹ ileesẹ naa ati awọn ọmọ ogun il Uganda to tete de sibi isẹlẹ naa, ni wọn pawọpọ da ibọn bo kiniun naa, to fi gbe ẹmi mi.

Igbesẹ naa si lo mu ko seese lati doola ẹmi ọkunrin to lewaju awọn to doju kọ kiniun naa, ti ko fi ba isẹlẹ naa lọ.

Awọn ara abule yari pe sisun lawọn yoo sun kiniun naa jẹ, ijọba fariga:

Amọ lẹyin ti wọn pa kiniun naa ni wahala miran tun suyọ nitori bi awọn ara abule mejeeji naa se ni oku kiniun naa lawọn alasẹ ko ni gbe lọ.

Wọn ni ọna lati gbẹsan awọn ohun ọsin awọn to pa ati bo se se awọn lese ni pe ki awọn pin ẹran ara kiniun naa lekiri lekiri, ki awọn si jẹ ẹ.

Iroyin naa ni awọn ara abule naa ja kiniun ọhun gba lootọ, ti gbogbo ẹbẹ awọn alasẹ UWA lati jọwọ oku kiniun naa fun wọn si ja si pabo.

Awọn alasẹ ni awọn ara abule naa pọ ju awọn lọ, ti agbara wọn si bori tawọn amọ awọn ara kiniun nikan ni wọn tii bo kawọn ọlọpaa to gba lọwọ wọn.

Wọn ni bakan naa ni wọn ge ori kiniun naa lati iyoku ara rẹ amọ gbogbo rẹ ni wọn ti ko lọ si agọ ọlọpaa bayii fun iwadii to yẹ

Atẹjade ti ileesẹ to wa fun akoso ẹranko igbẹ ni ilẹ Uganda fisita lori kiniun to wọ abule

Oríṣun àwòrán, UWA

A tọrọ aforijin lori bi kiniun se ya wọ abule yin - UWA

Wayio, awọn alasẹ ileesẹ to n se amojuto awọn ẹranko igbẹ lorilẹede Uganda naa ti wa tọrọ aforijin lọwọ awọn ara abule ti isẹlẹ naa kan.

Bakan naa ni wọn kẹdun pẹlu wọn nipa awọn ẹran ọsin ti wọn padanu ati ọgbẹ ti wọn gba lati ara isẹlẹ naa.

Ileesẹ UWA wa seleri pe oun yoo gbọ bukata to ba jẹyọ lori itọju awọn eeyan to fara gbọgbẹ lasiko ikọlu kiniun naa.

Wọn wa kede pe awọn ko tii mọ orisun ibi ti kiniun naa ti wa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀