Fresh FM Attacked: Adigunjalè kó dúkìá olówó iyebíye lọ ní iléeṣẹ́ Rédíò Yinka Ayefele

ileeṣẹ redio Fresh FM

Oríṣun àwòrán, other

Awọn adigunjale kọlu ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ redio Fresh FM to wa nilu Ibadan lowurọ ọjọ Aiku, nibi ti wọn ti gba ọpọlọpọ dukia alumọni lọwọ awọn oṣiṣẹ to wa lẹnu iṣẹ nibẹ.

Iroyin to kan wa lọwọ ṣalaye pe nnkan bii agogo mẹfa idaji ni awọn adigunjale naa de toun tawọn ohun ija oloro lọwọ, ti wọn si n gba gbogbo dukia ati owo to wa lọwọ awọn oṣiṣẹ to wa lẹnu iṣẹ.

Ẹnitan Oluṣẹgun Bamidele, EOB, to jẹ ọkan lara awọn ilumọọkan agbohunsafẹfẹ to n ṣiṣẹ nileeṣẹ redio naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC News Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bamidele ṣalaye pe lootọ oun o si ni gbagede ileeṣẹ naa lasiko ti iṣẹlẹ naa waye ṣugbọn ohun ti wọn fi to oun leti ni pe awọn adigunjale naa ṣọṣẹ kaakiri ileeṣẹ naa ṣugbọn wọn ko de inu yara igbohunsafẹfẹ.

EOB, gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe e, ni o ṣeeṣe ko jẹ pe ẹru ki oju wọn maa baa han loju ẹrọ akaworansilẹ Kamẹra to wa nibẹ, ni wọn ṣe wara ro.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa

Amọṣa, o ni ko fẹẹ si ibi ti ẹrọ CCTV kamẹra oju-mi-too ko si ni gbagede ileeṣẹ naa.

Bakan naa ni ọkan lara awọn ọga nileeṣẹ naa, Abọlade Salami pẹlu yannana bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, lasiko to fi n ṣe eto lowurọ ọjọ Aiku lori ikanni redio naa.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn alọ koloun kigbe naa ji ko ni lọ nileesẹ redio ọhun ni owo, ẹrọ ibanisọrọ atawọn dukia miran ti owo rẹ ko ṣee maa sọ.

Bawo lọrọ FreshFM ṣe jẹ?

Ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ redio Fresh FM ni ileeṣẹ redio ti gbajumọ akọrin ni, Yinka Ayefẹlẹ da silẹ ni ilu Ibadan nibi ti o ti wa gbẹrẹgẹjigẹ lọsawọn ilu miran bii Abẹokuta, Ado Ekiti, Osogbo ati Eko.

Ni ọdun 2018 ni ijba ipinlẹ Ọyọ labẹ gomina igba naa, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi da katakata si ileeṣẹ naa nilu Ibadan ti wọn si wo nitori edeaiyede to waye laarin ijọba ati ileeṣẹ redio naa nigba naa.

Bi o tilẹ jẹ pe lẹyin o rẹyin ina wọ laarin wọn ti gomina Ajimọbi si tun ileeṣẹ naa kọ pada.

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele