Pamilerin Ayanlere: Ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù, kí n tó di onílù Yinka Ayefele
Yoruba sọ pe ọmọ ti yoo ba jẹ aṣamu, ati kekere ni yoo ti ma ṣe ẹnu ṣamu-ṣamu.
Bayii gan-an ni ọrọ ri fun Oluwapamilerin Ayanlere, ọdọmọde to n fi ilu Gangan dara nilu Ibadan.
Gẹgẹ bi ọmọ naa ṣe sọ fun BBC Yoruba, igba to wa ni ọmọ ọdun mẹta lo ti bẹrẹ ilu lilu.
Eyi ko si ṣyin bo sẹ jẹ pe idile onilu ni wọn ti bi i.
- Ojú máa ń tì mí láti rẹ́rìn ín nítorí irú eyín ẹnu mi ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ mo padà dí arìnrìnoge- Omotola Ekundayo
- Ọwọ pálábá ọmọ ọdún 15 mẹ́ta tó fẹ́ fi èèyàn ṣe òògùn ségi
- Obìnrin kan ń pa ẹgbèrún méjìdínlógójì Pọ́ùn lọ́sẹ̀ fún isó títa
- Àrà mérìírí! Ìbejí tí a bí ní ọdun 2021 àti 2022 pẹ̀lú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dògún láàrin wọn
Ọmọ naa to wa ni ipele ẹkọ SS 2 nile ẹkọ girama ti di ọkan lara awọn to n lu ilu fun gbajugbaja olorin, Yinka Ayefele.
Yinka Ayefele sọ pe arimaleelọ ni ọrọ ọmọ naa jẹ fun oun ni ọjọ ti oun kọkọ ri to lu ilu nibi ayẹyẹ.
Nitori naa si ni oun ṣe pinnu lati gba a si iṣẹ.
