PDP Crisis: Mo fẹ kí èmi àti Auxillary kojú ara wa lọ́dọ̀ ọlọ́pàá ní Abuja lórí ìkọlù náà
Eekan oloṣelu kan lẹgbẹ oṣelu NNPP nipinlẹ Ọyọ, Alhaji Adebisi Ọlọpọeyan ti kọwe ẹdakun ẹ gbami ranṣẹ si ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria Usman Baba.
Bakan naa lo fi iwe ẹbẹ sọwọ si adari ileeṣẹ̀ alaabo DSS, Yusuf Bichi pe ko ṣeto ati fi panpẹ ofin gbe olori ajọ amojuto ibudokọ ero nipinlẹ̀ Ọyọ, PMS, Mukaila Lamidi ti ọpọ mọ si Auxilliary.
Awọn iwe ẹbẹ naa lo kọ nitori bi awọn afurasi janduku kan se ya bo ile rẹ lọjọ Aje, ti wọn si ba dukia olowo iyebiye jẹ ati bi wọn ti ṣe ọpọ eeyan leṣe pẹlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- A rí àwọn fọ́tò tó fihàn pé ọkọ Osinachi ní ìyàwó míràn sí ìkọ̀kọ̀ - Minisita ọrọ obinrin
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ Aláàfin, ẹni tó pààrọ̀ nǹkan obìnrin sí ti ọkùnrin
- Àṣírí ayédèrú ológun méjìlá tó ń gbégi dínà ní Ajah ati agbègbè míì tú sọ́wọ́ iléeṣẹ́ ológun
- Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Peter, ọkọ Osinachi, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú aya rẹ̀ kàn
- Ọdún mẹ́jọ ni ọkọ ọmọ mi kò jẹ́ ki n fojú kan ọmọ mi lẹ́yìn ìgbéyàwó - Ìyá Osinachi
- Kí ló dé tí ẹnu ń kun ìgbeyàwó Funke Akindele pé ó ti dàrú? Àbọ̀ ìwádìí wa rèé
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ tètè jápa tí ìgbéyàwó yín bá ti la ìgbájú-ìgbámú lọ - Olori Silekunola
- Ọwọ́ àwọn ológun kò mọ́ lórí ìkọlù agbébọn ní Nàìjíríà - Àwọn aṣòfin àpapọ̀ fọnmú
- Ṣe lóòótọ́ ni pé Osinbajo kìí se ọmọ ẹgbẹ́ APC l‘Eko?
- Èmi ni mo kájúẹ láti di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà – Tinubu
- Àjọ INEC ní àwọn káàdì ìdìbò kan kò wúlò mọ́ láti fi dìbò lọ́dún 2023
- Erin kọlu Amaya Sebastian, àgbà ọ̀jẹ́ ọjọ́gbọ́n nínú isẹ́ ìwádìí kan, ikú ló padà já sí
Ninu iwe ẹbẹ to kọ sawọn agbofinro naa si ni Olopoeyan ti kede pe Auxillary ni oun fura si pe o ran awọn janduku naa wa se isẹ ibi nile oun.
Eekan ẹgbẹ oṣelu PDP ni Alaaji Ọlọpọeniyan tẹlẹ, ki o to digba ati agbọn rẹ gba ẹgbẹ oṣelu NNPP lọ.
O ni bi gomina ipinlẹ̀ Ọyọ, Seyi Makinde ṣe n ṣakoso ẹgbẹ oṣelu naa lo sun oun kuro lagbo rẹ lọjọ Aje.
Gbogbo igba ni Auxillary maa n lepa ẹmi mi - Olopoeyan:
Lẹyin to gbe igbesẹ kuro lẹgbẹ oṣelu PDP lọ si NNPP yii, lawọn janduku kan, ti Alaaji Ọlọpọeniyan sọ pe oun furasi pe wọn jẹ ọmọ ajọ amojuto ibudo ero nipinlẹ naa.
Amọṣa o, ọwọ awọn ọlọpaa kogberegbe tẹ ọkan ninu wọn.
Alaaji Ọlọpọeniyan ṣalaye pe kii ṣe oni tabi ana ni Auxilliary ti n lepa ẹmi oun, ti oun si ti kọ ọpọ iwe ẹ gba mi ranṣẹ si awọn adari ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ agbofinro DSS.
O ni ikọlu naa fidi ohun ti oun ti n fi to ileeṣẹ ọlọ̀paa leti tipẹtipẹ ni ṣugbọn ọkan ninu awọn janduku naa ti awọn ọlọpaa mu lo jẹ ki oun mọ pe awọn mọ ikọ amojuto ibudokọ ero nipinlẹ Ọyọ ni afurasi naa jẹ.
Eekan oloṣelu naa ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti awọn "ọmọlẹyin Auxilliary" yoo maa kọlu oun; nitori pe wọn ṣe oun to jọọ eyi lasiko ti oun ṣi wa lẹgbẹ oṣelu PDP.
"Wọn kọlu wa nibi ipade idibo yan awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa to waye ni papa iṣire Liberty.
Ki ni esi ti Auxilliary fun Ọlọpọeyan?
Ninu ọrọ rẹ si ẹsun ti Alaaji Ọlọpọeniyan fi kan PMS ati alaga rẹ, Auxilliary, alukoro ajọ amojuto ibudokọero nipinlẹ Ọyọ, PMS ṣalaye pe irọ nla ni Alaaji Ọlọpọeniyan n pa.
O ni ahesọ lasan ni pe awọn ọmọ ajọ PMS lo kọlu ile oloṣelu naa nitoripe agbegbe Testing Ground niluu Ibadan ni iṣẹlẹ naa ti waye niwaju agọ ọlọpaa to wa ni Testing ground.
Awọn ọlọpaa ranṣẹ pe awọn kan lara awọn ọmọ wa, nigba ti wọn n kuro nibẹ lawọn janduku kan ti wọn jẹ ọmọlẹyin Alaaji Ọlọpọeniyan kọlu wọn ni oju titi nibẹ.
Awọn gan an ni ọdaluru o."
Rògbòdìyàn ṣẹlẹ̀ n'Ibadan, ọwọ́ tẹ jàǹdùkú nílé Olopoeyan pẹ̀lú káàdì ìdámọ̀ ẹgbẹ́ Auxillary

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe wahala nla bẹ sile nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo nigba ti awọn afurasi janduku kan ya bo ile eekan oloselu kan.
Oluwarẹ ni Alhaji Adebisi Olopoeyan, tii se alajọsepọ tẹlẹ ninu ẹgbẹ oselu PDP pẹlu gomina Seyi Makinde.
Olopoeyan, to n fapa janu lori bo se ni gomina Makinde n fi ọwọ rọ wọn sẹyin ninu ẹgbẹ PDP ati isejọba rẹ lo wa ni igun tinu n bi ninu ẹgbẹ oselu PDP tẹlẹ.
- Àṣìgbé ọmọ wọ́ọ̀dù ni Seyi Makinde - Àgbààgbà PDP l‘Oyo ka ẹ̀sùn sí gómìnà l'ẹ́sẹ̀
- Igun ìkejì ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Oyo ṣé ibura sípò fún alága tí wọ́n
- Á ṣiṣẹ́ tako Seyi Makinde fún sáà kejì - Igun PDP l‘Oyo fọnmú
- PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC
- À ǹ gbìyànjú láti yánjú àáwọ̀ àárín ẹgbẹ́ wa, àmọ́ àwọn èèyàn ló bẹ̀ mí kí n lọ fún sáà kejì
- "Ẹ̀yin dà, ẹ ní lógò, ọpẹ́ Seyi Makinde láye yin, kí ló ń jẹ́ PDP l‘Oyo tẹ́lẹ̀"
- APC ni Auxilliary ṣiṣẹ́ fún lásìkò ìdìbò gómìnà 2019 kìí ṣe PDP-Oyo NURTW
- Seyi Makinde pe olóyè PDP lẹ́jọ̀ fún ìbanilórúkọ jẹ́ lórí Facebook
Ki lo waye saaju ki janduku to kọlu ile Olopoeyan?
Adebisi Olopoeeyan lo kede lọjọ Aje pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP, ti oun si ti dara pọ mọ ẹgbẹ oselu New Nigeria People's Party, NNPP.
Nibi ayẹyẹ igbasagbo kan to waye nilu Ibadan lọjọ Aje ni wọn ti fi tilu-tifọn ki Olopoeyan atawọn alatilẹyin rẹ kaabọ sinu ẹgbẹ oselu NNPP.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ igbasagbo naa ni Olopoeyan ti sapejuwe gomina Makinde bii alaimoore.
Agba oselu naa salaye pe ibẹrẹ pẹrẹ ni oun ti gbe ẹgbẹ PDP ga lọdun 2015 fun Seyi Makinde lati moke ninu idibo gomina.
O wa fọwọ gbaya pe ọpọ ọmọ ẹgbẹ APC ati PDP nipinlẹ Oyo si ni wọn ti n palẹ mọ lati dara pọ mọ ẹgbẹ NNPP naa laipẹ laijinna.

Oríṣun àwòrán, Olopoeyan
Bawo ni ikọlu se waye sile Olopoeyan?
Ko pẹ ti ayẹyẹ igbasagbo naa pari ni awọn janduku kan ya bo ile agba oselu Adebisi Olopoeyan to wa ni Basorun/Idi Ape nilu Ibadan.
Se ni ọpọ eeyan to wa ni adugbo naa, titi to fi de orita Idi-Ape si Iwo Road fẹsẹ fẹ nigba ti wọn n gburo ibọn to n dun lakọ lakọ ati idagiri eeyan.
Idi ni pe wọn ro pe awọn adigunjale lo tun gbe ise wọn de ladugbo naa gẹgẹ bi wọn ti se nibẹrẹ ọdun yii.
Nigba ti wọn yoo si fi sẹju diẹ lẹyin isẹju melo kan, ọpọ eeyan, ti pupọ wọn jẹ alatilẹyin Olopoeyan, ti fara pa yanna-yanna.
Ọwọ tẹ afurasi janduku kan pẹlu kaadi idanimọ ẹgbẹ alakoso gareeji ọkọ labẹ Auxillary:
Bi o tilẹ jẹ pe awọn janduku naa raye na papa bora, amọ sibẹ ọwọ tẹ ọkan lara wọn.
Lasiko to si fẹ fẹsẹ fẹ pẹlu awọn yoku rẹ ni awọn eeyan gba ya a, ti wọn si mu silẹ.
Lara awọn nnkan ti wọn si ba lara afurasi naa ni kaadi idanimọ ọmọ ẹgbẹ alakoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, Parks Management System (PMS).
Alhaji Mukaila Lamidi, ti ọpọ eeyan mọ si Auxillary si ni adari ẹgbẹ PMS naa.

Oríṣun àwòrán, Olopoeyan
N ti maa jẹ ni mo n wa, emi kii se ara awọn janduku:
Ninu fidio kan to wa lori ayelujara nibi ti awọn eeyan ti n fi ọrọ wa afurasi ti wọn naa lẹnu wo.
Afurasi janduku naa, ti wọn ti bọ sokoto nidi rẹ de idaji, lo ti salaye pe oun kii se ara awọn janduku to wa sile agba oselu naa.
Bakan naa ni ko si asọ lọrun afurasi naa, to si din irun rẹ ni irun dada igbalode.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tí ẹnu ń kun ìgbeyàwó Funke Akindele pé ó ti dàrú? Àbọ̀ ìwádìí wa rèé
- Ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ l‘Eko láàrin igun MC Oluomo àti ẹgbẹ́ awakọ̀ márúwá TOOAN
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ tètè jápa tí ìgbéyàwó yín bá ti la ìgbájú-ìgbámú lọ - Olori Silekunola
- Ìdí tí Tinubu fi ṣèpàdé pẹ̀láwọn gómìnà APC lẹ́yìn tí Osinbajo kéde lati dupò ààrẹ
- Àwọn ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ òfin gbé ọkọ olórin ẹ̀mí “Ekwueme” fẹ́sùn lílu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn agbébọn pa ènìyàn 135 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Oko kìí jẹ́ ti baba tọmọ kó mà ní ààlà; Mi ò ní ọmọ tó dàgbà tó le jáde láti dupò Ààrẹ- Tinubu
Afurasi naa, to na kaadi idanimọ ti wọn ka mọ lọwọ soke, wa n bẹ awọn to mu pe ki wọn mase jẹ ki oun jẹ iya oniya nitori oun kii se ara awọn janduku to wa.
"Ẹ dakun, ẹ ma pa mi. Emi kii se ara wọn walahi, ọlọkada ni mi:
Iyawo mi sẹsẹ loyun ni, ọlọkada ni mi emi kii se ara wọn.
Mo ni ki n maa ta igbo yii ni boya Ọlọrun le saanu mi, n kii se ara wọn."
Amọ nibayii, wọn ti fa afurasi janduku naa le awọn ọlọpaa lọwọ.
Awa PMS ko mọ nkankan nipa isẹlẹ to waye nile Olopoeyan:
BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ẹgbẹ alakoso gareeji PMS nilu Ibadan, Wasiu Adebayo lati mọ iha ẹgbẹ naa si isẹlẹ ọhun.
Adebayo, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni awọn ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.
"A ko mọ nkankan nipa rẹ, tẹ ba bi wọn gan, wọn yoo sọ fun yin pe a ko mọ nkankan nipa isẹlẹ naa.
Awọn ole ni wọn sọ pe wọn wa jale ni adugbo yẹn, awa kan rin si asiko ti isẹlẹ naa waye ni.
Ohun to sẹlẹ nibẹ ko kan wa rara, a kan kọja ni akoko igba yẹn ni.
Ẹnikankan ko ba wn ja ninu awọn ọmọ ẹgbẹ PMS, awọn naa ko si ba wa ja, a kan kọja lọ nibẹ ni."
Wayio, ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti wa salaye pe ko si isẹlẹ idigunjale kankan to waye ladugbo Idi-Ape lọjọ Aje gẹgẹ bawọn eeyan kan se n sọ ahesọ ọrọ kiri.























