Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ

Àkọlé fídíò, Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ

Oniruuru laasigbo lo ti n ba ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo finra lati bi ọjọ melo kan, ti onigbo si ti da igbo si meji, ti ọrọ ti di konko jabele, kaluku lo n se tiẹ.

Idi ni pe awọn eeyan kan ti ta kete ninu ẹgbẹ naa, ti wọn si kọ ẹyin si gomina Seyi Makinde tii se ọmọ ẹgbẹ wọm ti ogiri ẹgbẹ PDP ni Oyo si ti lanu, ti ọpọ alaamu ti ri aaye wọ ibẹ.

Awọn igun ti ko ba gomina Makinde se papọ yii lo pe ara wọn ni igun PDP ti inu n bi, koda, wọn da se ipade abẹnu tiwọn lọtọ ni, ti wọn si mu ki igbimọ alasẹ PDP ni Oyo pin si igun meji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan lara awọn to n dari igun PDP ti inu n bi naa ni Alhaji AbdulRasheed Adebisi, ti ọpọ eeyan mọ si Ọlọ́pọ̀èèyàn, ẹni to ba BBC News Yoruba nipa idi ti igun wọn se n fi apajanu.

Olopoeyan ni Seyi Makinde wa ya pepele ẹgbẹ PDP lo ni, awọn ko si jẹ ko ba jẹ mọ awọn to ni ẹgbẹ lọwọ.

O fikun pe ọkọ aloku ni gomina n ra lati fa ohu ẹta horo eeyan mọra, to si n polongo rẹ lori ayelujara.

O ni igbesẹ naa fi han pe iṣẹ ati osi pọ ninu PDP ni eyi se n waye, to si ni gomina naa ni anfaani lati ko gbogbo eeyan mọra ninu ẹgbẹ atawọn alatako gan pẹlu.

Amọ nigba to n sọrọ nipa awọn eeyan to da PDP Oyo si meji naa, Akọwe alukoro fun ẹgbẹ naa, Akeem Adetunji ni o yẹ ki awọn eeyan naa se suru ni.

O ni gbogbo ohun ti ko to, ni yoo pada sẹkun, o si yẹ ki n gba Makinde laaye ko maa pin ere ijọba alagbada fiẹ diẹ titi yoo fi kan wọn.