Oyo PDP: Ó yẹ kí àwọn ọlọ́pàá mú Lere Olayinka torí ó ń fi ara rẹ̀ sí ipò tí wọn kò yàn án sí

Lere Olayinka

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

Ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹka ti ipinlẹ Oyo ti ke si awọn agbofinro lati fi ṣikun ofin mu ọgbẹni Lere Olayinka, to jẹ adari ikọ ipolongo ẹgbẹ naa ni iha Guusu-Iwọ Oorun Naijiria lori ẹsun pe o n fi ara rẹ si ipo ti wọn ko yan si.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin abẹle Daily Independent sọrọ, agbẹnusọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo, Akeem Olatunji sọ pe, agbẹnusọ lasan ni Olayinka jẹ si gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose.

O ni ko si ẹnikẹni to yan Olayinka si ipo kankan ninu ẹgbẹ PDP ni iha Guusu-Iwọ Oorun Naijiria, nitori naa ohun to n ṣe ko ba ofin ẹgbẹ naa mu.

Olatunji ṣalaye pe gbogbo ọgbọn ti Olayinka ati ọga rẹ n da ni lati da wahala silẹ ninu ẹgbẹ PDP ki wọn to sa lọ darapọ mọ ẹgbẹ APC.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "Lere Olayinka ni agbẹnuso gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, iyẹn Ayo Fayose, kii ṣe aṣoju tabi oṣiṣẹ ẹgbẹ PDP."

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

"Ta lẹni to fi si ipo adari ikọ ipolongo ẹgbẹ naa ni iha Guusu-Iwọ Oorun Naijiria? O kan mọọmọ fi ararrẹ si ipo naa ni."

Olatunji tẹsiwaju pe ohun ti Lere Olayinka ṣe jẹ iwa ọdaran, nitori ko ba ofin mu ko maa pe ara ni ẹni ti kò jẹ tabi ko fi ara rẹ si ipo ti wọn ko yan si.

O pari ọrọ rẹ pe "a ti kilọ fun Lere Olayinka ati ọga rẹ lati jawọ ninu fifi idarudapọ sinu ẹgbẹ osẹlu PDP nitori a mọ pe wọn le darapọ mọ ẹgbẹ keji ti a ba le wọn kuro ninu ẹgbẹ wa."

Àkọlé fídíò, Risikat Moromoke Azeez: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù- Wasiu