Inter-tribal Marriage: Bàbá mi kọ̀ láti bá mi sọ̀rọ̀ torí ọ̀kọ akáta tí mo mú wálé

Jona ati ẹbi rẹ

Tori iriri tirẹ, Jonah ti bẹrẹ si ni ṣe eto idanilẹkọ fawọn lọkọlaya afẹsọna lati gbaradi fun ọna ara ọtọ nipa bi wọn lee ṣafihan ololufẹ wọn to ba ṣajoji si ẹbi wọn.

Oun ni oludasilẹ Blindian Project to jẹ eto ori ayelujara to fi n yẹ awọn eeyan alawọdudu si latari irinajo ifẹ wọn pẹlu awọn ara Asia.

"Bawo ni mo ṣe le fi afẹsọna mi han fawọn obi mi". Eyi ni ibeere to Jonah maa n ri gba ju latọdọ awọn ara Asia to maa n kan si i.

"Niṣe lẹru n ba mi gaan to nira fun mi lati wo oju baba mi, gbogbo igba ni mo n doju bolẹ. Ọpọlọpọ ni ko ni ireti mọ nitori eyi".

Ajoṣepọ eto ti Jonah n ṣe pẹlu iyawo rẹ Swetha ni wọn n ṣe lati ṣeranwọ fawọn eeyan bii tiwọn to n ronu bi wọn ṣe le mu ọkọ tabi iyawo afẹsọna dele.

Àkọlé fídíò, Risikat Moromoke Azeez: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù- Wasiu

Jonah ati Swetha bẹrẹ eto ti wọn n ṣe yii lọdun 2017. Awọn ololufẹ mejeeji pade lọdun 2015 ti wọn si bẹr si ni yofẹ ara wọn lẹsẹkẹsẹ bo tilẹ jẹ pe wọn kii ṣe ọmọ orilẹede kan naa.

Wọn ri i wipe awọn jọ fran ohun kan naa to pọ loriṣiriṣi - ounjẹ, orin, afojusun iṣẹ, idagbasoke idile to jọrawọn.

Ti wọn ba n ṣe eto ori ayelujara yii, wọn ni ọpọ eeyan lo maa n bere fun imọran awọn ti ibeere to ma n wọpọ si jẹ "bawo ni mo ṣe le fi afẹsọna mi han fawọn obi mi".

Swetha ni "ẹru maa n ba awọn eeyan, awọn eeyan ni ọpọlọpọ iṣoro to tan mọ aṣa nibi ti wọn ti wa paapaa ni Asia".

O ni wọn maa n ronu bakan bakan boya nipa ohun ti awọn eeyan alawọdudu lee ṣe si tabi ko ran awọn ara Asia.

Eeyan kan tilẹ pe sori eto to n yọlẹ sọrọ kẹlẹ kẹlẹ torii pe ko fẹ ki awọn mọlẹbi rẹ gbọ ohun to n sọ.

"Mo ti wa pẹlu ololufẹ mi fun ọdun meji ati abọ bayii o si ti su mi ki n ma gbe igbe aye oloju meji".

O sọ fun Jonah pe aburo oun obinrin nikan loun ti sọ fun to si n gbero lati sọ fun gbọn rẹ ọkunrin naa laipẹ ki ọrọ tilẹ to lee kan awọn obi wọn rara.

"Ọkan mi n gbọn nipa ohun ti awọn obi wa maa sọ bi mo ba sọ fun wọn".

Jonah ati iyawo rẹ Swetha ti ran ọpọlọpọ eeyan lọwọ lati kọ wọn ni ọna ti wọn lee gba sọ fun obi wọn nipa ẹni ti wọn yan lati fẹ.

Sanya Salim

Oríṣun àwòrán, Sanya Salim

Ki lo le ṣe too ba ba ara rẹ nipo ẹni to di ololufẹ ọmọ orilẹede tabi ya mii?

Riri eeyan ti yoo to si ọ lẹyin ninu idile rẹ jẹ ohun kan.

Sanya Salim ni nkan toun ṣe niyii o si rii pe ẹgbọn rẹ kunrin lo kọkọ ri ololufẹ rẹ soju.

"Asiko kan wa ti baba mi kọ lati ba mi sọrọ fun ọpọlọpọ oṣu lẹyin ti mo s fun un nipa Michael, ẹgbọn mi lo ṣi aṣọ loju ọrọ eyi si ni ọrọ to tobi ju taa sọ papọ nipa ololufẹ mi".

Ẹwẹ, oniruuru iṣẹlẹ to ti ṣẹlẹ nilẹ Amẹrika laipẹ yii ti ja funrarẹ fun awọn eeyan alawọdudu laarin awn araa ilẹ Asia. Apẹrẹ ni ifẹhonuhan #Blacklivesmatter.

"Mo yaa kẹnu bọ ọ̀rọ̀ gbogbo ifhonuhan to buru taa ri, nigba ti Kamala Harris tun wọle ggẹ bi igbakeji aarẹ Amẹrika, mo n sọ fun iya mi pe ṣẹẹ mọ pe abẹyameji loun naa bi emi ati Michael".

Asiko ti oo tu kẹkẹ ọrọ naa ṣe pataki

"Mo lero wipe asiko ti a yan bọ si dede. Asiko ti awa sọ baba ọrọ ṣe kongẹ ohun daadaa fun wa, asiko ti ololufẹ meji lee ni ifọkanbalẹ lati jẹ ki awọn eeyan mọ wọn papọ ki wọn si maa ri wọn ni gbangba".

Jonah ati Swetha ni ireti pe iriri awọn ati igbesẹ iranwọ tawọn n gbe yoo ran awọn eeyan alawọdudu to wa ni Asia ati lagbaye lọwọ.

"Awọn ọmọ wa jẹ ọdun mẹrin ati mẹfa a si n jẹ ki wọn dagba papọ ti wọn si fẹran awọ ara wọn bo ṣe ba jade.

Awọn ọmọde