Students kidnap: Garba Shehu ní iléeṣẹ́ ológun ti yabo ibùdó àwọn jàndùkú tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ nílé ìwé katsina

Oríṣun àwòrán, AFP
Oluranlọwọ aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ iroyin, Garba Shehu ti sọ pe ileeṣẹ ologun ti ṣe awari awọn janduku agbebọn to ji awọn akẹkọọ ileewe girama to wa ni Kankara, nipinlẹ Katsina.
Shehu to fọrọ yii lede loju opo Twitter rẹ ṣalaye pe awọn ologun ti ṣe akitiyan lati doola awọn akẹkọọ to wa lakata awọn janduku ọhun.
O ṣalaye pe ninu igbo Zango/Paula ni Kankara lawọn sọja pẹlu itanlọwọ awọn ọmogun ofurufu ti ri awọn janduku ajinigbe naa.
- ''Buhari àti Tinubu ṣ'àdéhùn pé Yorùbá ni yóò jẹ́ olùdíje ipò ààrẹ APC lọ́dún 2023 ''
- Iléeṣẹ́ epo rọ̀bì ná ₦116m lórí báírò, ìwé ìkọ̀wé, àwọn aṣòfin fìka hánu
- Ara mi rẹwà ló jẹ́ kí n máa ṣí ara sílẹ̀- Victoria Kolawole
- Èyí ni bí gómìnà Babajide SanwoOlu ti ìpínlẹ̀ Eko ṣe kó COVID-19
- 'Ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n bọ́ mi sí ìhòhò, ó ki ìka rẹ̀ bọ ìdí mi látẹ̀yìn'
- Ìwà ìbàjẹ̀ bíi olé jíjà, ìjínigbé àti rìbá gbígbà ní Okediji fi ṣàpèjúwe ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà
- Kìí ṣe gbogbo ohun tí dókìtà ni kí n má jẹ torí àìsàn jẹjẹrẹ ni mo tẹ̀lé- Soyinka
Ninu atẹjade ti Shehu fi lede ọhun ni o ti sọ pe ko si ikankan to fara gbọgbẹ ninu awọn akẹkọọ ti wọn gbe lọ bo tilẹ jẹ pe awọn sọja atawọn agbebọn naa kọju ija si ara wọn.
Bakan naa ni Shehu sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, o si paṣẹ pe ki eto abo to nipan wa ni gbogbo ileewe.
Akẹkọọ mẹrinlelaadọta ni a gbọ pe awọn janduku agbebọn ọhun ji lọ lọjọ Ẹti nileewe to wa ni kankara ni Katsina.
Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ kete ti Buhari bẹrẹ abẹwo ọlọsẹ kan si ipinlẹ Katsina tii ṣe ipinlẹ rẹ.
Buhari kẹdun pẹlu awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn jigbe lọ atawọn alaṣẹ ileewe naa.
Ìjọba Katsina ti gbogbo ilé ìwé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé pa lẹ́yìn àkọlù tó wáyé níbẹ̀
Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ile iwe ti awọn akẹkọọ n gbe ni ipinlẹ naa pa.
Masari lo kede bẹẹ lẹyin ti awọn agbebọn kan ṣakọlu sile iwe awọn akẹkọọ to jẹ ọkunrin nikan loru ọjọ Ẹti, ti wọn si ji lara wọn gbe lọ.
Gomina ọhun ṣabẹwo sile iwe naa toun pẹlu igbakeji rẹ, Mannir Yakubu, ti wọn si ṣeleri fun awọn eeyan Kankara nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye pe ijọba apapọ yoo sa gbogbo ipa rẹ lati ṣawari awọn akẹkọọ to poora.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ko ṣeni to tii le sọ iye awọn akẹkọọ to di awati ni pato.

Oríṣun àwòrán, GALI KANKARA
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ni awọn n ṣe iwadii lọwọ, ṣugbọn iroyin ni ko din ni irinwo akẹkọọ to poora.
Ile iwe ọhuun, Government Science Secondary School, to jẹ ti awọn akẹkọọ ọkunrin nikan ní akẹkọọ to le ni ẹgbẹrin.
Awọn eeyan to n gbe lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ pe irinwo le mẹfa ni wọn ti ri lara awọn ọmọ ile iwe naa, ṣugbọn wọn ko le sọ ibi ti awọn to ku wa.
Àwọn jàndùkú agbébọn''jí akẹ́kọ̀ọ́ lọ nílé ìwé girama Katsina'' lẹ́yìn tí Buhari gúnlẹ̀ sí bẹ̀
Yoruba bọ wọn ni ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni nu lọ, eyi lo difa fun Gomina ipinlẹ Katsina to bẹ sẹkun gbaragada lẹyin tawọn janduku agbebọn yabo ileewe girama kan to wa ni Kankara, nipinlẹ Katsina nibi ti wọn ti ji ọpọ akẹkọọ lọ.
Iṣẹlẹ yii ṣẹ lẹyin wakati diẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari gunlẹ si ipinlẹ naa fun abẹwo ọlọsẹ kan.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ṣalaye pe ni aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Ẹti lawọn gbọ pe awọn janduku pẹlu ibọn AK47 lọwọ wọn yabo ileewe girama to wa ni Kankara.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọpọ awọn akẹkọọ lo sa asala fun ẹmi wọn nigba tawọn kọlọnbiti ẹda ọhun de ọgba ileewe wọn.
Koda ọga ọlọpaa DPO ṣalaye fawọn akọroyin pe akẹkọọ igba lo ti pada si ileewe naa lẹyin ti wọn ti sa sinu igbo lati alẹ ọjọ Ẹti.
Ileeṣẹ ọlọpaa lawọn si n ka awọn akẹkọọ lati mọ bo ya awọn janduku agbebọn naa ri awọn akẹkọ ji gbe lọ.
Ṣugbọn ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe lootọọ lawọn agbebọn ji awọn akẹkọọ lọ ni ileewe naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọga ọlọpaa naa fikun ọrọ rẹ pe awọn ọlọpaa to ṣọ ileewe ọhun kọju ija sawọn janduku naa nibi ti ọlọpaa kan ti farapa.
O ni ọlọpaa to ṣeṣe naa n gba itọju lọwọ bayii nile iwosan.
Iroyin kan sọ pe ilegbe awọn oṣiṣẹ to wa nile iwe naa lawọn ọdaran naa kọkọ lọ ni nibi ti wọn ti ji iyawo ọkan lara awọn gbe.
Lẹyin naa ni wọn lọ si ilegbe awọn akẹkọọ nibi ti wọn gbe awọn akẹkọọ ti ẹnikan ko tii mọ iye rẹ lọ.
Awọn kan tun sọ pe awọn ologun lọ si ileewe naa lati doola awọn akẹkọọ ṣugbọn wọn pada ji awọn akẹkọọ kan lọ.












