Dapo Ojora: Ẹ̀gbọ́n ìyàwó Bukola Saraki kú l'Eko, èdè aìyedè wà lórí bó ṣe kú

dapo ojora

Oríṣun àwòrán, Twitter/bukaola saraki

Ni alẹ ọjọ Ẹti ni iroyin jade sigboro pe, ilumọọka ọmọ jayejaye ilu Eko ni, Dapọ Ọjọra ti jade laye.

Yatọ si pe ẹni ọdun mejidinlaadọta ni, ohun to n ṣe ọpọ eeyan ni haa-hin bayii ni iroyin pe o yinbọn pa ara rẹ ni.

Dapọ jẹ ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja oniṣowo nni, Otunba Kunle Ojọra; oun si tun ni aburo fun Toyin Saraki to jẹ iyawo aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ lo n sọ kiri pe, Dapọ ṣeku pa ara rẹ ni, sibẹ Sẹnetọ Saraki ti sọrọ sita pe awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.

Atẹjade Saraki loju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, Olubayode Alebiosu

Ki ni ọlọpaa sọ?

Amọṣa, ileeṣẹ ọlọpaa ti ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iku wọọkilu mọ naa, lati mọ boya lootọ ni arakunrin naa gbẹmi ara rẹ.

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l'Eko, Olumuyiwa Adejọbi fi sita, wa rọ araalu lati gboju kuro nidi ohun tawọn akọroyin kan n sọ pe o ṣokunfa iku rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa bu ẹnu atẹ lu ahesọ iroyin gbogbo to n lọ nipa bi iku oloogbe naa ṣe waye.

dapo ojora

Oríṣun àwòrán, Thisdaylive

Femi Fani-Kayode atawọn eekan ilu mii n daro Dapo Ojora

Niwọn igba to jẹ pe bi ọdẹ ba ku, ọdẹ lo n ṣoro lẹyin ọdẹ, awọn eekanlu lorisirisis ti bọ soju opo ayelujara wọn lati daro Dapo Ojora to di oloogbe.

Lara awọn eekanlu naa lati ri Femi Fani-Kayode, ẹni to sọ loju opo Twitter rẹ pe o ba oun lọkan jẹ lati gbọ iku ọkunrin naa.

"O dun mi lati gbọ pe Dapo Ojoro ti lọ lẹyin ọdun mẹsan ta padanu Gbegi, ẹgbọn rẹ.

O ti to aadọta ọdun ti mo ti mọ Dapo, ta si jọ maa n gba Polo papọ, o si jẹ ọkan lara awọn alaanu ti mo sun mọ julọ."

Ọrọ idaro Femi Fani-Kayode

Oríṣun àwòrán, @realFFK